O ti le ni oṣu kan bayii ti gbajugbaja alagbata fiimu Yoruba, Ola Ibironke ti ọpọ mọ si Dudu Heritage fi ilẹ bora bi aṣọ amọ iyawo rẹ to jẹ gbajugbaja oṣerebinrin, Bimbo Oshin ṣi n ṣaaro rẹ.
Lasiko ti ọpọlọpọ n ṣe pọpọṣinṣin ọdun ti wọn n ṣe yọtọmi ti wọn si n fi oniruuru aworan ajọyọ ọdun sita lori ayelujara, paapaa awọn ojulumọ ti eeyan mọ, ṣe ni Bimbo Oshin sọ ọrọ to fi ọwọ kan ni lọkan sita.
Ọpọlọpọ fọto ifẹ wn laye atijọ ni o ko jade sori ayelujara lati fi daro ololufẹ rẹ to ti dagbere fun un laye.
Loju opo rẹ lo fi fọto oun ati ọkọ rẹ, oloogbe Dudu Heritage si to si kọ ọrọ pe eyi ni asiko Keresimesi akọkọ fun gbogbo ọdun mọkanlelogun igbeyawo awọn ti ko ba oun ṣe.
“Ayẹyẹ ọdun Keresi akọkọ ree ifẹ mi! egungun ẹyin mi, maa simi lọ lọwọ ẹlẹda rẹ. Ọkọ mi, a n ṣaaro rẹ”.
Ṣe ni awọn akẹgbẹ rẹ rọ si oju opo rẹ lati tu u ninu.