Kí ló ṣẹlẹ̀ tí a fi ń pé ọjọ́ kejì Kérésì ní ‘Boxing Day’?

Boxing Day

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Itan ‘Boxing Day’ yii bẹrẹ lakoko ti Ọọbabirin Victoria wa lori aleefa niwọn ọdun 1800.

Boxing Day ko ni nnkankan ṣe pẹlu ẹṣẹ kíkàn gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe lero.

Orisun orukọ naa bẹrẹ pẹlu bi awọn ọlọla ṣe maa n di ẹbun sinu apoti, ti wọn si maa n pin fun awọn alaini lọpọlọpọ ọdun sẹyin.

Boxing Day

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọjọ ọhun jẹ ọjọ ti awọn ẹru kii ṣe iṣẹ kankan, ti awọn olowo wọn si maa n fun wọn ni ẹbun ọdun Keresi ninu apoti.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awọn ẹbun ọhun ni awọn ẹru naa maa n gbe lọ fun awọn ara ile wọn ki wọn fi ṣafihan bi awọn olowo awọn ṣe mọ riri iṣẹ ti wọn ṣe lodindin ọdun kan to.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

‘Boxing Day’ tun jẹ ọjọ ti awọn orilẹ-ede kan bii Hungary, Germany, Poland ati Netherlands maa n ṣe ajọyọ ọjọ to tẹle ọjọ ọdun Keresimesi.

Ipa ti ijọ ko

Ninu iwe itan, awọn ile ijọsin naa kopa ninu ṣiṣagbekale ọjọ ‘Boxing Day’to wa fun pinpin ẹbun fi mọ riri ara ẹni.

Lẹyin ti wọn ba ti gba owo ọrẹ lọwọ awọn ijọ laarin ọdun, wọn maa n ko owo naa sinu apoti, wọn a wa ṣi apoti owo ọrẹ yii lọjọ keji ọdun Keresi, ti wọn a si pin owo inu rẹ fun awọn talaka.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọjọ wo ni ọjọ Boxing Day?

Boxing Day jẹ ọjọ keji, ọdun Keresimesi, o si maa n bọ si ọjọ kẹrindinlọgbọn, ninu oṣu Kejila ọdun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọjọ ọhun tun jẹ ọjọ isinmi lorilẹ-ede Naijiria ati ni awọn orilẹ-ede miran lagbaye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lorilẹ-ede wa nibi, ọjọ yii jẹ ọjọ faaji ati ọjọ igablejo loriṣiriṣi fun ọpọ eeyan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọjọ ọhun tun jẹ ọjọ ti awọn eeyan ma jẹ ajẹyo ati ajẹṣẹku ounjẹ ti wọn se lasiko ọdun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ