Amotekun dóòlà èèyàn mẹ́sàn án lọ́wọ́ àwọn ajínigbé lọ́jọ́ Kérésìmesì l’Osun

Amotekun

Oríṣun àwòrán, @SaharaReporters

Awọn ẹṣọ Amotekun doola eeyan mẹsan an ti ọmọde meji wa ninu wọn lọwọ awọn ajinigbe nipinlẹ Osun lọjọ Keresimesi.

Lopopona Ilesha si Akure lagbegbe Ipetumodu ni iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ nigba tawọn eeyan naa n rinrin ajo lati ilu Eko lọ si Ado-Ekiti.

Awọn ẹṣọ Amotekun ipinlẹ Osun ati Ondo ni wọn jọ ṣiṣẹ pọ ṣe aṣeyọri naa.

Ni bii ọjọ melo sẹyin ni awọn alaṣẹ Amotekun lawọn ipinlẹ Yoruba da awọn ẹṣọ Amotekun si awọn ibode ipinlẹ Ondo, Osun, Ekiti ati Ogun.

Igbesẹ yii waye lati le dẹkun awọn ọdaran to ba fẹ ṣiṣẹ ibi papaa julọ lasiko pọpọṣinṣin ọdun.

Ọga agba Amotekun kaakiri ilẹ Yoruba, Oloye Adetunji Adeleye ṣalaye pe awọn ẹṣọ bẹrẹ iṣẹ kete ti wọn tawọn lolobo nipa ohun to ṣẹlẹ.

”Ni bii ago oru ọjọ Keresimesi lawọn ẹbi awọn eeyan ti wọn ji gbe pe wa pe awọn ajinigbe ti n beere owo itusilẹ lọwọ awọn.

Bayii ni a bẹ sinu igbo, ti a si ri awọn ọdaran ajinigbe naa nibi ti wọn wa pẹlu awọn eeyan ti wọn ji gbe.

Gbogbo awọn ti wọn ji gbe ni a doola wọn, ṣugbọn awọn ọdaran ajinigbe naa salọ.

A ṣe akiyesi pẹlu awọn nkan ti a ri ni akata awọn ajinigbe pe wọn ti n maa ko awọn eeyan ti wọn ba jigbe pamọ sibẹ.

Awọn eṣọ wa ṣi wa ninu igbo nibi ti wọn ti n wa awọn ajinigbe oniṣẹ ibi yii,” Oloye Adeleye ṣalaye.

Nigba to n ṣalaye ohun ti oju wọn ri lakata awọn ajinigbe, Ife Balogun to n lọ fun ọdun Keresimesi nilu Ado-Ekiti ṣalaye pe awọn ajinigbe ọhun ti ko owo pamọ sinu igbo fuj ọpọ wakati ki awọn ẹṣọ Amotekun to de.