Desmond Tutu, Àlùfáà tó wú ni lórí àti ajìjàgbara eléyàmẹ̀yà tó jáde láye, ohun tẹ́ẹ ní láti mọ̀ rèé

Desmond Tutu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Desmond Tutu ni olórí bíṣọ́ọ̀bù tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn fẹ́ràn káàkiri agbáyé.

Gẹ́gẹ́ bíì àlùfáà aláwọ̀dúdú pàtàkì, o di ẹni tí ó ní láti dá si ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yàmẹ̀yà, ṣugbọ́n gbogbo ìgba ni ó máa ń sọ wípé nítorí ẹ̀sìn ni òun ṣe dá sí ọ̀rọ̀ náà, kìí ṣe nítorí òṣèlú.

Nelson Mandela yàn áń gẹ́gẹ́ bíi olórí àjọ àpejorò to ṣe ìwádii àwọn ìwà ọ̀darǹ tó ṣẹlẹ̀ nígbà ẹlẹ́yàmẹ̀yà ní South Africa.

Òun ni ó sọ South Africa ní orílẹ́èdè òṣùmàrè lẹ́yìn tí ẹlẹ́yàmẹ̀yà parí nítorí oríṣiríṣi ẹ̀yà to bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe pọ̀.

Ọdún 1931 ni wọ́n bí Desmond Mpilo Tutu ní ìlú kékeré kan tí wọ́n ti ń wa góolù ní Transvaal.

Ó kọ́kọ́ tẹ̀lé ìṣisẹ̀ bàbá rẹ̀ láti di olùkọ́, ṣùgbọ́n ó fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n fi òfin ẹ̀kọ́ Bantu ti 1953 lé lẹ̀ nínú èyí tí ọ́n ti fi dá ẹlẹ́yàmẹ̀yà sílẹ̀ ní ilí ìwé.

Ó dara pọ̀ mọ́ ìjọ tí ó sì tọ ipasẹ̀ àwọn àlùfáà aláwọ̀ funfun, ní pàtàkì, Bíṣọ́ọ́bù Trevor Huddleston tó lódì sí ẹlẹ́yàmẹ̀yà.

Desmond Tutu pẹ̀lú àwọn ọmọ ilé ìwé ní 1961

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹ́yìn tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àlùfáà, Tutu gba oyè ‘divinity’ àti ‘sociology’ ní fasiti London, o sì ṣe àlùfáà fún ìgba ráńpẹ́ ní ilé ìjọsìn méjì ní Ilẹ Gẹ́ẹ̀sì.

Lẹ́yin ìgbà ránpẹ́ ní Ilẹ Gẹ̀ẹ́si pẹ̀lú ‘World Council of Churches’ ó di olórí àlùfáà kíní fún Johannesburg ni 1975.

Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi bíṣọ́ọ́bù Lesotho ní 1976 sí 78, igbákejì bíṣọ́ọ́bù Johannesburg ati amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ka ìjọ tó wà ní Soweto ki ó tó di bíṣọ́ọ́bù Johannesburg.

Ìgbà tó jẹ́ olórí àlùfáà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ohùn rẹ̀ sókè lórí ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yàmẹ̀yà ní South Africa.