Kàyééfì! Wo àlàyé sáyẹnsì lórí ìdí tí aláboyún tó ní ilé ọmọ méjì ṣe bí ọmọ méjì láàrin ọjọ́ méjì

Aworan aláboyún tó bi ìbejì

Oríṣun àwòrán, ANDREA MABRY/UNIVERSITY OF ALABAMA AT BIRMINGHAM

Ara mee riri leleyii taa mu tọyin wa.

O si ni ohun ṣe pẹlu bi alaboyun kan to ni ile ọmọ meji ṣe bi ọmọ meji laarin ogun wakati si arawọn to bẹrẹ si ni rọbi ọmọ.

Kelsey Hatcher, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn bi ọmọ obinrin kan ni ọjọ Iṣẹgun to si bi ọmọ keji lỌjọru ni ile iwosan to wa ni ile ẹkọ fasiti Alabama lorileede Amẹrika.

Loju opo ayelujara to ti kede ibimọ iyalẹnu yi o ṣapejuwe awọn onimọ ilera to gbẹbi rẹ gẹgẹ bi “alara gbayida.”

Wọn sì ti ṣapejuwe awọn ibeji obìnrin rẹ yi gẹgẹ bi ibeji ti wọn ko yato si ọmọ iya meji.

Idi ni pe aatọ meji ọtọọtọ lo ro papọ mọ ẹyin meji ọtọọtọ to pada doyun ninu iya wọn.

Ọjọ ibi awọn mejeeji ko ni papọ tori eleyi.

Arabinrin Hatcher sọ pe awọn ti padà sile t’awọn yoo si tẹsiwaju lati gbadun isinmi ọdun.

Ṣaaju lo loun ro pe ọjọ ọdun loun yoo bi awọn ọmọ naa si.

Nigba ti wa lẹni ọdun mẹtadinlogun ni wọn sọ fun iya ikoko yi pe o ni ile ọmọ meji, nkan ti ko wọpọ laarin awọn obinrin.

Bakan naa ni wọn sọ fun pe ati gboyun sinu ile ọmọ mejeeji jẹ nkan to sọrọ lati ṣẹlẹ gẹgẹ bi ile ìwòsàn fasiti to bi awọn ibeji yi si ṣe salaye.

Kaakiri agbaye akọsilẹ iru ìṣẹlẹ yi sọwọn.

Lọdun 2019 dokita kan ni Bangladesh sọ fun BBC pe alaboyun kan bi ọmọ ibeji lẹyin oṣù kan to bi ọmọ ti ọjọ rẹ ko pe lati inu ile ọmọ rẹ keji.

Ṣaaju asiko yi arabinrin Hatcher ti bi ọmọ mẹta mii tí iru nkan bayi ko waye.

Lọtẹ yi o sọ pe oun ni igbagbọ pe oyun inu ile ọmọ kan loun ni ki ayẹwo to wa sọ pe ọmọ wa ninu ile ọmọ ẹlẹẹkeji.

Iyalẹnu lo jẹ fún to si ṣe akọsilẹ oyun yi s’oju opo Instagram rẹ.

Aworan Hatcher

Oríṣun àwòrán, ANDREA MABRY/UNIVERSITY OF ALABAMA AT BIRMINGHAM

Ile iwosan UAB to gbẹbi rẹ sọ pe ko si wahala kankan pẹlu oyun to ni.

Ọjọgbọn Richard David to pẹlu awọn to gbẹbi rẹ sọ pe ọmọ kọọkan gba aaye lọtọ ninu ile ọmọ ti wọn wa eyi to mu ki wọn dagba daada.

O ni idi ni pe ile ọmọ wọn yatọ sí tàwọn ibeji to ṣe pe inu ile ọmọ kanna ni wọn jijọ wa.

Oṣù kọkandinlogoji ni o fi gbe oyun yu t’awọn oṣiṣẹ ile iwosan ko si fi igba kankan moju kuro lara rẹ.

Oniwosan to gbẹbi rẹ sọ pe ariwo sọ nigba ti ọmọ alakọkọ de gba oju ara iya rẹ ni nkan bi ago mẹjọ ku iṣẹju mẹẹdogun lọjọ kọkandinlogun oṣu Kejila.

Ẹlẹẹkeji waye gba ọna iṣẹ abẹ lẹyin nkan to le wakati mẹwàá ni nkan bi ago mẹfa kọja iṣẹju mẹwàá l’owurọ ọjọ Kejì.

Ọjọgbọn Davis sọ pe awọn le pe awọn ibeji yi ni ibeji meji to waye lati inu ile ọmọ ọtọọtọ.

Ẹyin ọtọọtọ ni wọn gbe waye ti o si jẹ aatọ ọtọọtọ lo darapọ mọ ẹyin wọnyii.

“Bi a ba pada foju wo ọmọ meji naa lọ wa ninu ikun kan ṣoṣo.Yara ọtọọtọ ni wọn kan n gbe ninu ibẹ”