Emefiele padà rí béèlì gbà lọ́wọ́ ilé ẹjọ́

Aworan Godwin Emefiele

Oríṣun àwòrán, Others

Gomina tẹlẹ fun bank apapọ lorilẹede Naijiria, Godwin Emefiele ti gba itusilẹ kuro ni ọgba ẹwọn Kuje lẹyin to gba beeli.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kejilelogun, oṣu Kejila ọdun 2023 ni Emefiele kuro ni ọgba ẹwọn Kuje.

Agbẹnusọ ọgba ẹwọn Kuja, Adamu Duza fidi ọrọ naa mulẹ fun ileeṣẹ iroyin abẹle Punch.

“Mo le fìdi rẹ mulẹ fun yín pe Emefiele ti ri beeli gba, to si ti kuro ni ayika ọgba ẹwọn.

“O ri beeli gba ni ọjọ Ẹti, ọjọ kejilelogun, oṣu Kejila ọdun 2023.”

Ile ẹjọ gíga to n joko niluu Abuja lo fun Emefiele ni beeli N300m lórí ẹsun ṣíṣe owo ilu mọkunmọku to wa lọrun rẹ.

Adajọ Hamza Muazu lo gbe idajọ naa kalẹ, ti Emefiele si pese oniduro meji.

Bakan naa ni Adajọ palasẹ pe ki Emefiele fi gbogbo iwe irinna rẹ kalẹ fun ile ẹjọ.

Ẹsun ìwa ajẹbanu lasìko to wa nípo gẹgẹ bí gomìna CBN ni Emefiele n kojú.

Ẹsun ogun tí apapọ owo rẹ le ni bílíọnu mẹfa ni ìjọba apapọ kọkọ ka sí Emefiele lọrùn lati kojú ìgbẹjọ le lórí.

Amọ ìjọba apapọ ti mu àdínkù bá iye ẹ̀sùn náà sí mẹfà tí owó rẹ sì lé bilíọnu kan naira ni ile ẹjọ lọjọ Ẹtì.

Emefiele kówó pamọ́ sí àkáúǹtì 593 ní orílẹ̀-èdè US, UK àti China – Olùwádìí CBN

Aworan Godwin Emefiele

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gomina banki apapọ Naijiria, CBN, tẹlẹ ri, Godwin Emefiele ko ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu naira pamọ sinu akaunti 593 lorilẹede Amẹrika, UK àti ni China eleyii ti igbimọ adari ati ìgbimọ idokowo CBN ko mọ si.

Oluwadii pataki banki CBN, Jimi Obaze lo sọ ninu abajade iwadii rẹ pe Emefiele ko £543,482,213 sí apo ikowosi l’awọn banki kan lorilẹ ede UK lai gba aṣẹ.

Ọjọru to lọ yii ni Obaze fi abọ iwadii rẹ lori banki apapọ CBN atawọn nkan mii to jọ mọ ransẹ sí aarẹ Bola Tinubu.

Abọ iwadii naa fidi rẹ mulẹ pe gbogbo akaunti ti Emefiele kowo pamọ si yii ni oluwadii ti ṣe awari rẹ.

Emefiele to wa ni ọgba ẹwọn Kuje niluu Abuja lo n jẹjọ lori ẹsun gbigbe N1.2bn jade l’ọna aitọ.

Beeli ọdunrun un naira ti ile ẹjọ giga ijọba apapọ fun un lọjọ kejilelogun oṣu Kọkanla ko tii kẹsẹ jari.

Amọ, iroyin kan fidi rẹ mulẹ pe afaimọ ki gomina banki apapọ Naijiria CBN tẹlẹ ma tun bẹrẹ si ni jẹjọ lori awọn ẹsun tuntun míràn atunṣe owo naira.

Emefiele ko gbaṣẹ lọwọ Buhari

Oluwadii CBN fidi rẹ mulẹ pe Emefiele ko gba aṣẹ lọwọ aarẹ ana Muhammadu Buhari lori ati ṣe owo naira tuntun.

Oludamọran Buhari, Tunde Sabiu lo kọkọ sọ fun Emefiele loṣu Kẹsan an ọdun 2022 pe ko se atuntẹ owo naira.

Ọjọ kẹfa oṣu Kẹwaa ọdun 2022 ni Emefiele kọ lẹta si Buhari pe oun fẹ ṣe atuntẹ owo N1000, N500 ati N200.

Amọ, Buhari ko buwọlu atuntẹ owo naa gẹgẹ bi o ti yẹ labẹ ofin.

Buhari kan buwọlu igbesẹ lati tẹ owo naira sii ni.

Ẹnu lasan ni Emefiele fi sọrọ atuntẹ owo naira fun igbimọ adari CBN lẹyin ti o ti gbe iṣẹ atuntẹ owo naira tuntun naa sita.

Iwadii tun fihan bi CBN labẹ aṣẹ Emefiele ṣe N26.627tn ni ina kuna ati bi owo ti ijọba ya sọtọ fun itọju covid-19.