Ṣé lóòtọ́ ni ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ṣíná ìbọn fún òṣèré tíátà Yoruba, Azeez Ijaduade?

Ijaduade Ololade Azeez

Oríṣun àwòrán, alaodc21/kingzeez1

Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe ọlọpaa kan ti dana ibọn ya oṣere tiata Yoruba, Azeez Ololade Ijaduade, lagbegbe Iperu, nipinlẹ Ogun.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, oṣerẹ naa, to tun jẹ oludari fiimu ti wa nile ẹkọ ẹkọṣe iṣegun Babcock University Teaching Hospital niluu Ilishan-Remo, nibi to ti n gba itọju lọwọ.

Ọkan lara awọn akẹgbẹ rẹ, Abiodun Adebanjo lo fi ọrọ naa lede loju opo Instagram rẹ ni afẹmọju ọjọ Aiku.

Atẹjade naa ni “Ẹ jọwọ a nilo iranlọwọ niluu Iperu.

“Ọlọpaa ti yinbọn fun oludaru fiimi mi, Azeez Ijaduade, o si ti wa ni Babcock University Teaching Hospital bayii fun itọju.

Abiodun Adebanjo

Oríṣun àwòrán, Abiodun Adebanjo

“Ẹ jọwọ ki ẹnikẹni to ba ni nọmba ọga agba ọlọpaa patapata tabi ti kọmiṣọna fi ṣọwọ si wa.”

Ẹwẹ, ojugba rẹ mii nidi iṣẹ tiata, Rotimi Salami ti sọ pe ara Ijaduade ti n bale nile iwosan to wa.

Ọpọ awọn ololufẹ oṣere naa lo si ti n fi adura ranṣe si i.

A ko tii le sọ ohun to ṣẹlẹ ni pato ati bi ọrọ naa ṣe jẹ.

Salami Rotimi

Oríṣun àwòrán, Salami Rotimi

Bẹẹ naa ni Abiodun Adebanjo to fi ọrọ ọhun lede ko ṣalaye ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa ati ibi ti ọrọ de duro.

Gbogbo igbiyanju BBC Yoruba lati kan si alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Omolola Odutola lati tan imọle si ọrọ ọhun lo ja si pabo lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.