Ìwà àìlajú ní Russia hù bó ṣe kọlu ọ̀wọ̀n ìràntí ìṣekúpani – Ukraine

Ibudo ẹrọ alatagba ti Russia ju ado oloro si to n se eefin

Oríṣun àwòrán, @MFA_Ukraine

Ileesẹ to wa fun ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Ukraine ti kede pe iwa ailaju ni orilẹede Russia hu pẹlu bo se kọlu ẹrọ alatagba tẹlifisan to wa lẹba ọwọn iranti sekupani ọlọgọọrọ.

Ọwọn iranti naa ni wọn fi n se iranti awọn eeyan to jalaisi lasiko ogun abẹle keji ni Babyn Yar.

Babyn Yar yii lo jẹ ọkan lara iwa isekupani ọlọgọọrọ si ẹya Juu lasiko ti awọn Nazi n pa eeyan kiri nigba ogun abẹle keji.

Ibudo ọwọn iranti naa lo ni awọn ọpọ ohun manigbagbe lati fi se iranti awọn eeyan to ku.

Bakan naa ni ibudo ọhun tun ni ibudo iranti miran fun awọn ọmọde to ku lasiko isekupani naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Loju opo Twitter rẹ, ileesẹ ọrọ ilẹ okeere ni Ukraine salaye pe “Ikọ ologun Russia lo yin ado iku mọ ẹrọ alatagba naa to wa lẹba gbadege Babyn Yar.”

O fikun pe “Awọn ọdaran lati Russia naa ko duro rara ninu iwa ailaju ti wọn n hu. Russia tumọ si Ara oko.”

Amin iyasọtọ kan

Kílódé tí NATO kò ṣe fẹ́ gbè lẹ́yìn Ukraine?

Àjọ ìṣọ̀kan orílẹ̀ èdè ìwọ̀ Oòrùn àgbáyé ń kó àwọn ọmọ ogun lọ sí ìlà oòrùn Yúròpù ṣùgbọ́n wọn kò gbèrò láti dá sí ìjà tó ń lọ láàárín Russia àti Ukraine.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kíni NATO?

NATO – North Atlantic Treaty Organization – jẹ́ àjọ ọmọ ogun tí àwọn orílẹ̀ èdè méjìlá dá sílẹ̀ lọ́dún 1949 tó fi mọ́ orílẹ̀ èdè US, Canad, UK àti France.

Àwọn orílẹ̀ èdè tó wà nínú ẹgbẹ́ yìí fẹnukò láti máa ran ara wọn lọ́wọ́ nígbà tí ọ̀kan nínú wọn bá ń kojú ìṣòro láti òkèrè.

Ọmọ ogun

Èròńgbà ìdásílẹ̀ rẹ̀ ní láti kojú ìdúnkokò ogun Russia ní Yúròpù.

Ní ọdún 1955, Russia dá ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogún àwọn orílẹ̀ èdè ìlà oòrùn tó fi mọ́ sílẹ̀ láti fi fèsì sí NATO èyí tí wọ́n pè ní Warsaw Pact.

Nígbà tí Soviet Union pín lọ́dún 1991, gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Warsaw Pact bẹ̀rẹ̀ sí ní pín tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn sì di ọmọ ẹgbẹ́ NATO tí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ sì fi pé ọgbọ̀n báyìí.

Kílódé tí NATO kò ṣe fẹ́ gbè lẹ́yìn Ukraine?

Ukraine kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ́ NATO, fún ìdí èyí kò pọn dandan fún NATO láti gbèjà Ukraine.

Ukraine ti fẹ́ darapọ̀ mọ́ NATO fún ọjọ́ pípẹ́ ṣùgbọ́n Russia kò fẹ́ kí NATO gba Ukraine wọlé.

Russia ń bẹ̀rù pé NATO tí ń wọ ẹkùn òhun nípa gbígba àwọn orílẹ̀ èdè ìlà oòrùn sínú àjọ rẹ̀ àti pé bí Ukraine bá fi le darapọ̀ mọ́ NATO á jẹ́ wí pé òhun fí iná sórí òrùlé sùn, tí òhun gba ọ̀tá láyè sí ẹ̀yìnkùnlé òhun.

Akọ̀wé NATO, Jens Stoltenberg ti bu ẹnu àtẹ́ lú bí Russia ṣe ń ṣe ìkọlù sí Ukraine.

Aworan

Ipa wo ní NATO ní ìlà oòrùn Yúròpù ?

NATO ti ní ọmọ ogun ní tó ń gbòòrò láti ilẹ̀ olómìnira Baltic ní árìwá lọ sí Romania ní gúúsù.

Ní ọdún 2014, lẹ́yìn tí Russia gba Crimea ni wọ́n kó wọn dà sí ibẹ̀ láti máa ṣe alamí nítorí tí Russia bá fẹ́ gbọ́wọ́ ogun.

Ìkọlù Russia sí Ukraine ló ti ń fa awuyewuye láàárín àwọn orílẹ̀ èdè ìlà oòrùn Yúròpù. Kò dín ní ọmọ ogun ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì tí NATO ti dà sí àwọn orílẹ̀ èdè ìlà oòrùn Yúròpù tó pààlà pẹ̀lú Russia.

Stoltenberg ní gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn ni àwọn yóò dá ààbò bò.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Báwo ni NATO ṣe pọn kún ààbò kí ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ láàárín Russia àti Ukraine?

Ṣaájú kí ìjà náà tó bk sílẹ̀, US da àwọn ọmọ ogun tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta sí Poland àti Romania láti dá ààbò ibòdè àwọn orílẹ̀ èdè tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ NATO tí àwọn ọmọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ mìíràn sì wà ní sẹpẹ́.

Bákan náà ni US fi nǹkan ìjà ogun tí owó rẹ̀ tó igba mílíọ̀nù dọ́là ráńṣẹ́ sí Ukraine tó fi mọ́ Javelin, missiles àti àwọn nǹkan ìjagun mìíràn.

ohun èlò ìjà ogun

Bẹ́ẹ̀ náà ni UK àwọn ọmọ ogun ráńṣẹ́ sí Poland àti Estonia àti àwọn nǹkan ìjà ogun sí Ukraine.

Denmark, Spain, France àti Netherlands náà fi àwọn ọmọ ogun àti àwọn nǹkan ìjà ogun ráńṣẹ́ sí àwọn orílẹ̀ èdè ìlà oòrùn Yúròpù àti Mediterranean.