Ṣé lóòtọ́ ni pé Russia yóò kógun ja Naijiria àti pé ọmodébìnrin Ukraine gbéná wojú ọmọ ogun Russia?

Ukrainian girl confronting a Russian soldier

Aworan ọmọdebinrin kan, ti wọn ni o jẹ ọmọ orilẹ-ede Ukraine to n koju ọmọ ogun ilẹ Ressia ti bẹrẹ si n fa ori ayelujara ya ni Naijiria bayii.

Ninu aworan naa ni ọmọdebinrin ọhun ti wa niwaju jagunjagun naa, ti awọn eeyan si n pe ọmọ naa ni akinkanju nitori bo ṣe n gbena woju ọmọ ogun ilẹ Russia.

Amọ ṣe lootọ ni ọmọ naa jẹ ọmọ orilẹ-ede Ukraine to si n gbena woju ọmọ ogun ilẹ Russia nitori bi Russia ṣe gbe ogun ka orilẹ-ede rẹ mọle?

Iwadii wa nileeṣẹ iroyin BBC ti fi han pe ọrọ ko ri bẹẹ o.

Aworan ọhun ko wa lati orilẹ-ede Ukraine, koda ọmọ ogun naa ki ṣe ọmọ ogun ilẹ Russia.

Tani ọmọdebinirin yii ati jagun-jagun naa?

Orilẹ-ede Palestine ni wọn ti ya aworan naa, orukọ ọmọ naa si ni Tamini Ahed.

Ahed jẹ ọmọ ọdun mọkanla nigba ti wọn ya aworan naa lọdun 2012, nibi to ti n koju ọmọ ogun orilẹ-ede Israel.

Bo tilẹ jẹ pe o ṣoro diẹ lati fidi rẹ mulẹ pe aworan naa ki ṣe lati Ukraine, amọ irufẹ aṣọ ti ọmọ naa wọ, to fi mọ bi oju ọjọ ṣe ri ninu aworan ọhun fi han pe kii ṣe Ukraine ni wọn ti ya aworan naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bakan naa, aṣọ ti sọja naa wọ ati ibọn ọwọ rẹ fi han pe kii ṣe ti orilẹ-ede Russia.

Vitali Klitschko gbe ibọn lọwọ loju ogun

Aworan miran to ti n milẹ titi ni Naijiria ni ti abẹsẹkubiojo to tun jẹ gomina ilu Kiev, ni Ukraine, Vitali Klitschko to gbe ibọn lọwọ.

Lootọ, Klitschko lo wa ninu aworan naa, amọ inu oṣu kinni ọdun 2021 ni aworan naa kọkọ jade loju opo Instagram, kii ṣe aworan lati oju ogun to n lo lọwọ ni Ukraine bi ọpọ eeyan ṣe lero.

Fidio ikọlu Russia si Ukraine

Fidio miran to n fa ori ayelujara ya ni Naijiria ni ibugbamu kan ti wọn ni o ṣafihan bi Russia ṣe n da seria fun Ukraine.

Ukrainian girl confronting a Russian soldier

Irọi ni o! Ọjọ kẹrin, oṣu Kẹjọ, ọdun 2020 ni ibugbamu naa waye nibi ti wọn n ko awọn ohun ija ogun si ni “Port of Beirut,” lorilẹ-ede Lebanon.

Lakotan, awọn eeyan ti bẹrẹ si n pin fidio kan lori Twitter ni Najiria to jẹ ija to n waye ni Ukraine.

Russia war

Oríṣun àwòrán, Chris Kehinde Nwandu

Ileeṣẹ Twitter ti yọ fidio naa danu bayi nitori wọn ni o lodi si ofin to gbe ileeṣẹ awọn kalẹ.

Ukrainian girl confronting a Russian soldier

Iroyin kan naa to n to n gbode kan bayii ni pe Aarẹ Russia ti n leri tantan pe oun yoo gbe ogun ka Naijiria mọle, amọ irọ nla ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ