Fídíò, Nítòótọ́ àfọ́jú ni mí sùgbọ́n kò sí mọ́tò tí mi ò le ṣe nítorí iṣẹ́ tí mo kọ́ láti ilẹ̀ ni, Duration 5,37

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Samuel Sobakin: Ọdún mẹ́ẹ̀dógún sẹ́yìn ni ojú bẹ̀rẹ̀ sí ní dùn mí tí àwọn dókìtà sì ní Glaucoma ló fàá

Ẹni kejì ta jọ wà ní ibi iṣẹ́ máa ń rànmí lọ́wọ́ láti mú irinṣẹ́- Samuel Sobakin

Opọ̀ eeyan lo ggba pe ipenija ko da eeyan duro lori isẹ́ ori ba ran an.

Bẹ́ẹ̀ naa ni ọ̀rọ̀ Alagba Samuel Sobakin ri to jẹ́ omo Abeokuta ni ipinle Ogun sugbon to n tun ọkọ̀ se ni ilu Ibadan nipinlẹ̀ Oyo ti o wa ni guusu iwo oorun Naijiria.

Samuel salaye fun BBC pe: Iṣẹ́ tí mo kọ́ ni tí mo sì mọ̀ nípa rẹ̀ dáadáa mi ò sì fẹ́ tọrọ bárò ló jẹ́ kí n gbájúmọ.

Bawo ni oju Samuel Sobakin se fọ́?

Samuel Sobakin salaye ni kikun fun BBC bi ipenija oju yii se bere ko to wa maa dun un de ibi pe ko riran mo.

O so ipa ti awon omo ati eni ti won jo n sise n ko lati ran an lowo lenu ise naa.

Bakan naa ni BBC ba lara awon onibara Samuel Sobakin to jẹ́ akọ́sẹ́mọ́sẹ́ atokose naa sọ̀rọ̀ ti wọ́n si royin ọgbọ́n ori rẹ̀ ati iwa omoluwabi to fi n sise mekaniiki naa.

Samuel gba awon to ni ipenja ara ni imoran lati ma ro ara wọ́n pin ki wọ́n si ma se ọ̀lẹ tabi maa tọrọ bárà.

Samuel Mekaniiki to ni ipenija oju