Ilé ẹ̀kọ́ Chrisland School, àwọn òṣìṣẹ́, olùtajà tó wà níbi tí Whitney Adeniran ti kú yóò farahàn níwájú adájọ́

Ile ẹkọ Chrisland

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ijọba ipinlẹ Eko ti fi ọrọ mii sita lori ẹsun mimọ nipa iku ((eyi ti kii ṣe taara) ati iwa pipa eniyan ti ti wọn fi kan ile ẹkọ Chrisland, awọn oṣiṣẹ wọn to fi mọ olutaja kan.

Eyi n waye latari iku ọmọde kan to jẹ ọmọ ọdun mejila akẹkọ ile ẹkọ Chrisland, Whitney Adeniran.

Ọfiisi oludari ọrọ to kan araalu ni ẹka eto idajọ ipinlẹ Eko sọ ninu atẹjade kan ni ọjọ Ẹti, sọ pe wọn yoo gbe awọn afurasi naa lọ sile ẹjọ itagbangba (coroner’s inquest) lati jẹjọ lori ẹṣẹ to lodi si abala 224 ati 251 ninu iwe ofin Naijiria nipa iwa ọdanran ati iwe ofin ti ipinlẹ Eko ti ọdun 2015.

Bawo ni Whitney ṣe ku?

Whitney Adeniran

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Iroyin ti a gbọ ni pe Whitney Adeniran dede ṣubu wọọ silẹ lasiko ti wọn n ṣe eto idije ojule si ojule (Inter-house sport) ni ile ẹkọ wọn ni ọjọ kẹsan oṣu keji.

Lẹyin ti wọn ṣe ayẹwo oku ọmọde naa ni o fihan pe latara gigan mọ ina ni o fi ku.

Oniruuru ọrọ ati fa ki n faa lo jẹ jade lori iku ọmọ yii, lẹyin eyi ni ijọba ipinlẹ eko nipasẹ adajọ agba orilẹede Naijiria ati kọmisọna fun eto idajọ nipinlẹ naa, Moyosore Onigbanjo paṣẹ pe ki wọn ṣe igbẹ́jọ́ ìtagbangba (coroner) lati tan ina wa ohun to ṣokunfa iku Whitney.

Adari igbẹjọ Coroner naa, Olabisi Fajana lo pada kede wipe igbẹjọ yii yoo bẹrẹ ni ọjọ kẹrin oṣu kẹrin.

Gẹgẹ bo ṣe wa ninu atẹjade naa: “Ni ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹta ọdun 2023 ni igakeji ọga ọlọpaa fi ọrọ igbaninimọran rẹ jade lorii iwadii ileeṣẹ ọlọpaa lori iku Whitney pe awọn ti ri aridaju ẹsun ipaniyan (eyi ti kii ṣe tààrà) ati aibikita ati pipa eniyan ti wọn si fidi rẹ mulẹ labẹ ofin, awọn ti wọn si ri ẹsun yii lọwọ wọn gẹgẹ bi ofin ṣe sọ ọ ni, ileẹkọ naa, awọn oṣiṣẹ wọn kan ati ọkan lara awọn olutaja ọjọ naa”.

Nitori eyi ni atẹjade naa sọ pe wọn yoo farahan niwaju adajọ fun iwadii lori awọn ẹṣẹ to lodi si ofin orilẹede Naijiria ati ti ipinlẹ Eko.