Ikú ṣọṣẹ́! Òṣèré Yorùbá Gbemi Anjola dágbére fáyé

Gbemi Anjola

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Iroyin to n tẹ wa lọwọlọwọ ni wipe ọkan lara awọn oṣerebinrin lagbo tiata Yoruba ti jẹ Ọlọrun nipe.

Iroyin to wa lori ayelujara sọ pe alẹ ọjọ Ẹti ni oṣere naa to ti n di irawọ to n tan laarin awọn ẹlẹgbẹ rẹ gbẹmi mi nile iwosan.

Awọm akẹgbẹ rẹ ti n fi atjade sita bii aworan abẹla ninu okunkun, oju opo wọn pẹlu awọ dudu ti awọn mii si ti bẹrẹ si ni lo aworan rẹ lati fi ṣe idaro rẹ.

Ṣaaju iku rẹ ni Gbemisola ti n ba aisan jẹjẹrẹ ni agbegbe ile ọmọ fa a to si n gbadura fun ilera pipe amọ ọlọjọ ni asiko to.

Ọrọ idagbere

Oríṣun àwòrán, iteledicon1

Bakan naa, akẹgbẹ rẹ to ti fi ọrọ idagbere soju opo rẹ, Ibrahim Yekini ti ọpọ mọ si Itele D Icon ti ṣaaju fi aworan rẹ sita nigba kan ti o fihan bi arabinrin naa ṣe ru to tun dudu eyi to si gbẹ aworan mii to fi bo ṣe ri rumurumu tẹlẹ han.

Itele fi aworan naa bẹbẹ fun iranwọ awọn ẹlẹyinju aanu tun Gbemi: “Mi o tilẹ mọ ohun ti mo le kọ, eleyi ba ni ninu jẹ gidi. Amọ nitori orukọ Ọlọrun ẹjọwọ ẹ jẹ ka doola ẹmi Gbemi… Dokita sọ pe o ni arun jẹjẹrẹ.”

Gbemi Anjola

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gbemi ti n di oju ti gbogbo eeyan bẹrẹ si ni mọ lagbo oṣere ti ọpọlọpọ awọn akẹgbẹ rẹ si fẹran rẹ.

Ohun ati Itele ti jọ ṣiṣẹ papọ lori itage awọn ere oniruuru eyi si lo fi ibaṣepọ wọn han ti Itele ko ṣe lee pa a mọra lati pe fun iranwọ fun Gbemi.

Awọn iroyin sọ pe ara rẹ tilẹ ti n ya to si ti n pada sori itage diẹ diẹ ko to di pe o jẹ Ọlọrun nipe.