Ẹ má yá owó ra ẹran ọdún Ileya- Alfa ṣé ìkìlọ̀ fún àwọn Mùsùlùmí

Aworan

Bi ọdun ileya se n sumọ, awọn adari ẹsin ti gba awọn Musulumi ni imọran lati ma ko irẹwẹsi ọkan ba arawọn, ki wọn si se ọdun ni iwọn arawọn.

Awọn alfa ọhun lasiko ti wọn ileesẹ iroyin abẹle, The Punch sọrọ gba awọn musulumi ni iyanju lati wa isọ Ọba allah lasiko ọdun, ki wọn si gbiyanju lati ma se ya owo fi ra ẹran ọdun.

Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ, Ọjọgbọn Taofeek Abdulazeez kilọ fun awọn Musulumi pe yiya owo ẹran ọdun ko tọna ati pe ki wọn ra ẹran ti apa wọn ba ka.

“Ki awọn musulumi ra ẹran ti apa wọn ba ka. Ki wọn tẹ Ọlọrun Allah lọrun nikan, ki wọn si ma se ju agbara wọn lasiko yii.

“Wọn ko gbọdọ yawo ra ẹran lasiko ọdun ileya.”

Ọjọgbọn tẹsiwaju pe pataki ọdun ileya ni lati se iranti bi Anọbi Ibrahim(AS) se fi ara rẹ jin fun Ọlọrun ọba Allah

Ki n se dandan fun musulumi lati pa ẹran ọdun Ileya – Sheikh Tajudeen Adewunmi

Akọwe agba fun ẹgbẹ awọn imamu nipinlẹ Ogun, Sheikh Tajudeen Adewunmi ni o se koko ki awọn musulumi ma se se ju arawọn lasiko ọdun Ileya.

O ni ” Ko pọn dandan fun Musulumi lati pa ẹran, awọn to ba ni agbara lati ra ẹran ki wọn tẹsiwaju. Allah ko ki n jẹ ẹjẹ tabi ko ma jẹ ẹran.

“Nkan to fẹ lati ọdó wa ni pe ka bẹru ré ka si tun tẹle ilana rẹ.”

Bakan naa, igbakeji imamu fasiti ti ilu Abeokuta, Ọjọgbọn Sharafadeen AbdulKareem ni “Ko jẹ itẹwọgba pe ki Musulumi ya wo nitori ko lagbara lati ra ẹran .

“Sugbọn to wa ninu ẹgbẹ alajẹsẹku, ti wọn si setan lati ya lowo fun ọdun ileya, o le tẹsiwaju.”