Wo bí Meta ṣe fẹ́ fòpin sí gbígbà tábi fífi fọ́tò àti fídíò ìhòhò ránṣẹ́ lórí Instagram

Aworan ori Instagram

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ileeṣẹ Meta to ni itakun ayelujara Instagram ti ṣe agbekalẹ eto kan ti yoo dẹkun gbigba tabi fifi fidio ati fọto ihoho ranṣẹ tabi lilo rẹ lati tabuku eeyan lori Instagram.

Meta gbe eto yii kalẹ lati daabo bo awọn ọdọ lori bawọn eeyan kan ṣe maa n fi fidio ati fọto ihoho ṣọwọ si wọn ninu apo atẹjiṣẹ wọn ti wọn n pe ni ‘’direct message.’’

Ọna kinni ti eto naa yoo fi maa ṣiṣẹ ni pe irufẹ atẹjiṣẹ to ba jẹ fọto tabi fidio ihoho ko ni han to ba ti de ọdọ ẹni ti wọn fi ranṣẹ si papaa julọ ti ẹni naa ba jẹ ọdọ langba.

Meta ṣalaye pe iṣoro mẹta ọtọtọ loun fẹ fi eto naa koju lori Instagram.

Akọkọ ni pe nigba mii awọn ọdọ maa n gba atẹjiṣẹ fọto tabi fidio ihoho ti wọn ko beere fun tabi ti wọn ko tẹ fẹ ri gan an.

Ekeji ni fifi fọto ihoho awọn ọdọ ransẹ lori Instagram, koda ko jẹ wi pe awọ ọdọ gan an lo n fi fọto ihoho ara wọn ranṣẹ le lodi sofin.

Ẹkẹta ni pe nigba mii awọn maa n tan awọn ọdọmọkunrin lati fi fọto ihoho ara wọn ranṣẹ eyi ti wọn maa n lo fun ibanilorukọjẹ.

Ọpọ eeyan lo ti tako ileeṣẹ Meta to ni Instagram ni Yuroopu ati America pe lilo itagun ayelujara Instagram n fa arun ọpọlọ fun ọpọlọpọ ọdọ.

Amọ, Meta ti sọ pe awọn ti lo imọ ijinlẹ ṣe nkan ti ko ni maa jẹki fọto ihoho eeyan ko han lori Instagram mọ papaa julọ to ba ti jẹ pe ọdọ ni yoo gba atẹjiṣẹ naa.

Ileeṣẹ naa sọ pe oun maa lo imọ ijinlẹ lati mọ irufẹ atẹjiṣẹ DM to ni fọto tabi fidio ihoho.

O ṣalaye wi pe kete ti ileeṣẹ naa ba ti mọ pe ọdọ ni ẹni ti wọn fi atẹjiṣẹ ọhun ranṣẹ si nipa ọjọ ibi wọn ni awọn yoo ṣe e ti fọto naa ko fi ni han daadaa ti ikilọ yoo si tẹle e.

Adajọ agba ni ipinlẹ mẹtalelogun lorilẹede America lo gbe ileeṣẹ Meta lọ ile ẹjọ loṣu Kẹwaa ọdun 2023 lori ẹsun pe ileeṣẹ naa ṣi awọn lọna lori ewu to rọ mọ lilo awọn itakun ayelujara Instgram ati Facebook.

Nilẹ Yuroopu, ajọ EU naa ti beere alaye lori bi ileeṣẹ Meta ṣe n daabo bo awọn ọmọde pẹlu awọn nnkan to le ṣakoba fun wọn tawọn eeyan kan n fi lede lori awọn itakun ayelujara ileeṣẹ naa.