Ìpàdé ẹgbẹ́ òṣèlú APC yóò wáyé lónìí, wo ohun tí wọ́n fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC ń se ipolongo ita gbangba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress yoo ṣepade ni oni ọjọ Aiku lati jiroro lori ọjọ pato ti wọn yoo ṣe ipade apero gbogbo gbo eyi ti yoo ṣaaju idibo abẹle wọn.

Eyi waye ni idahun si iru ikilọ ti aarẹ Naijiria, Muhammadu Buhari fi sita ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ amohunmaworan NTA l’Ọjọbọ ọsẹ nibi to ti ni ki wọn tete wa wọrọkọ fi ṣe ada ki ituka ma baa ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ wọn.

Ninu ifọrọwerọ naa ni Aarẹ Buhari ti ni bi wọn ṣe da oni da ọla ti wọn n fi nkan falẹ, ẹgbẹ APC kan n fi ara wọn si eti bebe ijakulẹ ni lọwọ ẹgbẹ oṣelu alatako wọ, Peoples Democratic Party ninu idibo ọdun 2023.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nigba ti alaga ẹgbẹ awọn gomina iha Ariwa naa ṣepade pẹlu Aarẹ Buhari lọjọ Ẹti, Simon Lalong ni koko ohun ti awọn yoo maa ṣepade le lori lọjọ Aiku ni yiyan ọjọ ti ipade apero nla ẹgbẹ naa yoo waye.

Ni bayii, gbogbo awọn gomina APC ti ṣetan fun ipade oni lati yan ọjọ ti wọn yoo ṣe e.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, Aarẹ Buhari ti ni onyẹ kankank ko ni yẹ wiwaye ipade apero wọn ninu oṣu keji ọdun yii.

BAkan naa lo tọka sii pe ikilọ aarẹ Buhari pe ki wọn to ile wọn jẹ ohun to yẹ ki awọn ẹgbẹ mu lọkunkundun.