Ilé ẹjọ́ ju Mínísítà sẹ́wọ̀n ogún ọdún fún ìwà àjẹbánu

Algeria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ilé ẹjọ́ ní orílẹ̀ èdè Algeria ti sọ Mínísítà fọ́rọ̀ agbára nígbà kan rí ní orílẹ̀ èdè náà, Chakib Khelil sí ẹ̀wọ̀n ogún ọdún fẹ́sùn kíkówó ìlú jẹ.

Ilé ẹjọ́ Sidi M’Hamed tún ní kí Kheil tó ṣe Mínísítà lábẹ́ Ààrẹ Abdelaziz Bouteflika fún ọdún mẹ́wàá tún san owó ìtanràn mílíọ̀nù méjì dinars.

Bákan náà ni adarí ilé iṣẹ́ epo rọ̀bì àti afẹ́fẹ́ gáàsì Sonatrach orílẹ̀ èdè náà, Mohamed Meziane náà rí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún he pẹ̀lú owó ìtanràn mílìọ̀nù dinar kan.

Nibo ni ọ̀rọ̀ de duro bayii?

Meziane wà ní àtìmọ́lé báyìí fún ẹ̀sùn mìíràn.

Ní ọjọ́ kìíní, oṣù kejì, tí ìgbẹ́jọ́ Khelil àti Meziane bẹ̀rẹ̀, àwọn ẹ̀sùn mìíràn tí wọ́n tún fi kàn wọ́n ni pé, lásìkò tí wọ́n fi wà nípò, wọ́n ń lo ipò wọ́n láti fi hu àwọn ìwà tí kò tọ́.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lára àwọn ẹ̀sùn náà ni pé wọ́n máa ń gbé iṣẹ́ jáde láì tẹ̀lé ìlànà àti òfin tó yẹ àti fífi àyè tí kò tọ́ gba àwọn ènìyàn.

Ní ọdún 2010 ni Khelil, ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́rin báyìí, fí ipò rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mínísítà tó sì kó lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nígbà tí wọ́n dá orúkọ rẹ̀ mọ́ àwọn tó lọ́wọ́ nínú ìwà àjẹbánu ní ilé iṣẹ́ Sonatrach.

Algeria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ó padà sí Algeria lọ́dún 2016 lẹ́yìn tí ẹjọ́ náà rọlẹ̀ ṣùgbọ́n tó tún padà sí Amẹ́ríkà lọ́dún 2019 lẹ́yìn tí ẹjọ́ náà tún rú nígbà tí Bouteflika kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀.

Ẹ̀wẹ̀, Khelil kò sí ní ilé ẹjọ́ nígbà tí adájọ́ ń ṣe ìdájọ́ náà.