Ṣé Putin yóò tẹ bọ́tìnì lílo àdó ikú bí?

Vladimir Putin

Oríṣun àwòrán, ANADOLU AGENCY VIA GETTY IMAGES

Aarẹ orilẹede Russia, Vladimir Putin ti kede pe oun ti gbe orilẹede oun sabẹ igbaradi digbi lati se ikọlu nigba kuugba pẹlu ohun ija ado iku (Nuclear Weapon)

Bakan naa lo tun n fapa janu lori ‘ọrọ itara’ tawọn asaaju orilẹede to wa labẹ ajọ Nato sọ lori isẹlẹ to n waye ni Ukraine.

Bẹẹ ba si gbagbe, aarẹ Putin ti se ikilọ saaju lọsẹ to kọja pe “ẹnikẹni to ba n gbero lati da si aawọ Russi ati Ukraine lati ita – ni oju wọn yoo ri ohun ti oju ẹnikẹni ko ri ri ninu itan.”

“Awọn ọrọ ti aarẹ Putin sọ yii lo n dun bii idunkooko taarata lati lo ado iku bii ohun ija.” Eyi ni igbagbọ alami ẹyẹ Dmitry Muratov.

Amọ ti aarẹ Vladimir Putin ba pinnu lati bẹ́rẹ si fi ado iku ja, se ẹnikẹni to jẹ alabasepọ sun mọ le da duro bi?

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Awọn ọlaju ni ẹka oselu lorilẹede Russia kii fara mọ ero araalu rara, se ni wọn maa n to sẹyin awọn adari wọn.

Aarẹ Vladimir Putin ti Russia yi i si ni alasẹ to lagbara julọ nitori awọn adari orilẹede Russia ko ni olufisun tabi atọnisọna.

Ohun gbopgbo ti alasẹ wọn ba ti sọ, abẹ lo ge lai si ẹni ti yoo yẹ lọwọ wo, bẹẹ si ni ko si ẹnikẹni to le gbena woju Putin.

Ẹ ri pe ipo to lewu gbaa la wa bayii.” Pavel Felgenhauer.

Ogun to n waye yii si la le pe ni ogun Vladimir Putin.

Ti asaaju orilẹede Russia naa ba fi se imusẹ afojusun lilo ẹka ologun rẹ, boya ni ọjọ ọla orilẹede Ukraine lati jẹ orilẹede olominira yoo fi wa si imusẹ.

Amin iyasọtọ kan

Wo nkán táwọn olórí Nàìjíríà, orílẹ̀-èdè àgbáyé ń sọ nípa ikọlù Russia sì Ukraine

Aworan awọn olori lagbaye

Awọn olori orileede kaakiri agbeye ti n fesi si iṣẹlẹ ikọlu ti Russia ṣe si Ukraine lowurọ Ọjọb.

”Oni jẹ ọkan lara awọn ọjọ ti buru ju ninu akọsil itan Yuroopu lati igba ti ogun agbaye ẹlẹẹkeji ti waye” ni ọrọ ti olori ọrọ ilẹ okere EU Josep Borrell sọ.

O ni alagbara agbaye to ni ikapa nkan ija ogun Nuclear to si tun dunkoko mọ awọn alabagbe rẹ ati ẹni ba da si ọrọ jẹ iyapa si ofin agbaye.

Bẹẹ lo sọpe o o wa ni ilodi si ofin ijẹmọniyan ti o kere julọ.

O fi kun ọrọ rẹ pe EU yoo gbe ijiya to le julọ kalẹ lori Russia nitori nkan to ṣẹlẹ yi.

Ninu ọrọ tirẹ olori ajọ EU Ursula Von der Leyen bẹnu atẹ lu aarẹ Russia Vladimir Putin pẹlu bo ṣe ”da ogun pada wa si Yuroopu”

Lasiko to n kede ijiya to gbọngbọn tawọn yoo gbe kalẹ lori Russia lo kede ọrọ yi.

O ni awọn ijiya yi yoo ṣakoba fun eto ọrọ aje Russia ati agbara to ni lati dagbasoke.

Kete ti aarẹ Vladimir Putin kede ibẹrẹ eto ologun pataki yi ni agbegbe Donbas to wa ni ila oorun Ukraine ni Ursula fesi yi

Ninu ọrọ to sọ lori ẹrọ amounmaworan, aarẹ Putin ni ki awọn ọmọ ogun Ukraine to n koju awọn ọmọ ogun ọlọtẹ ti Russia n gbe lẹyin wọn ko nkan ogun silẹ ki wọn si pada sile.

Arakunrin Putin sọ pe Russia ko lerongba lati gba ilẹ Ukraine ṣugbọn awọn ko ni kẹr lati koju nikẹni to ba doju ija kọ awọn.

Nkan tawọn olori agbaye n sọ nipa iṣẹlẹ yi ree:

  • Minisita fọrọ ilẹ okere Ukraine fẹsun kan Russia pe fẹ da ogun silẹ ti o si kesi ajọ iṣẹkan agbaye UN lati ṣe gbogbo ipa lati dẹkun Russia
  • Aarẹ Amẹrika Joe Biden sọ pe oun bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ yi to si ni awọn yoo pe Russia lẹjọ lori iwa yi
  • Awọn olori lati il Gẹẹsi, EU,UN, ati NATO lo koro oju si iwa ti Russia wu yi
  • Agbẹnusọ orileede Germany kan sọ pe olori ilẹ naa Chancellor Olaf Scholz ti ba aarẹ Ukrain Volodymyr Zelenskiy sọrọ ati pe awọn wa lẹyin rẹ bi ike.
  • Olootu ijọba il Gẹẹsi Boris Johnson sọ pe ọrọ naa fọwọ kan oun lẹmi lori ikọlu ti ko yẹ yi ati pe ilẹ Gẹẹsi yoo fesi lalae bikita
  • Aarẹ ajọ European Commission, Ursula von der Leyen, naa ti bẹnu atẹ lu Russia pe wọn fẹ da ogun pada si ilẹ Yuroopu.
  • Olootu ijọba Italy, Mario Draghi sọ pe igbesẹ yi ko bojumu ko si fẹsẹ mulẹ rara ati rara

Ki ni orileede Naijiria sọ nipa iṣẹlẹ yi?

Atẹjade kan lati ileeṣẹ ọrọ ilẹ okere Naijiira to tẹwa lọwọ sọ pe iyalẹnu ni iroyin kọlu Russia si Ukraine yi jẹ fun Naijiira.

Agbẹnusọ ileeṣẹ naa Fransisca Omoyuli sọ pe ileeṣẹ ilẹ okere Naijiira to wa ni Ukraine n gbiyanju lati daabo bo ko si gbe awọn ọmọ Naijiria to ba wa ni Ukraine pada wa sile.

Iyẹn fawọn to ba wu lati ṣe bẹẹ.

Lọwọ bayi wọn ko ti ṣe awọn papakọ ofurufu to wa ni Ukraine ṣugbọn ijọba Naijiria sọ pe awọn yoo ṣeto fawọn ọmọ ilẹ naa lati kuro kete ti wọn ba si papakọ ofurufu.