Àwọn agbébọn yabo ibi ètò ìgbéyàwó, jí ìyàwó gbé lọ

Àwọn agbébọn

Oríṣun àwòrán, others

Bí ènìyàn bá ti dá ọjọ́ ìnàwó sọ́nà ní ọkàn rẹ̀ yóò ti ga tí yóò sì máa gbàdúrà kí ọjọ́ kò láyọ̀. ki àwọn agbébọn ma ba a ni alejo.

Ọ̀rọ̀ kò fẹ́ rí bẹ́ẹ̀ fún ìyàwó tuntun yìí bí àwọn agbébọn tí iye wọn fẹ́ẹ̀ tó ọgọ́rùn-ún ṣe ya wọ àwọn ìlú kan ní ìjọba ìbílẹ̀ Lavun, ìpínlẹ̀ Niger.

Àwọn agbébọn náà ni ìròyìn ní wọn yabo ibi ìgbéyàwó náà tí wọ́n sì jí ìyàwó gbé lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bákan náà ni wọ́n pa ènìyàn mẹ́jọ, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì farapa níbi ìkọlù náà.

Lára àwọn ìlú tí wọ́n ṣe ìkọlù sí ni Egbako, Ndaruka, Ebbo, Ndagbegi, Tshogi, Gogata àti Ndakogitu.

Ní alẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta ní ìkọlù náà bẹ̀rẹ̀ títí di àárọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ Àìkú.

Kí ni àwọn agbébọn náà ṣe?

Ní ìlú Gbacitagi, àwọn agbébọn náà yabo ibi igbéyàwó, jí ìyàwó, ọmọdébìnrin kan, owó àti àwọn ohun èlò mìíràn gbé lọ.

Bákan náà ni ìròyìn ní wọn pa ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní Ebbo, Tsonfadagabi, Tsoga àti Kanko tí wọ́n sì ba àwọn ọkọ̀ jẹ́.

Kọmísọ́nà fétò ìjọba ìbílẹ̀ ìpínlẹ̀ Niger Emmanuel Umar fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kí ni àwọn ara ìlú ṣe fún àwọn agbébọn náà?

Àwọn fijilanté gbìyànjú láti kojú àwọn agbébọn náà léyìí tó fà á kí wọ́n dojú ìbọn ko ara wọn.

Fijilanté méjì àti àwọn ara ìlú mẹ́rin ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ