Àwọn tó kọ́ ojúbọ òrìṣà sáàrín ìgboro Eko kó sí gbaga òfin

Awọn mẹjọ tọwọ ba pe wọn kọ ojubọ oriṣa saarin ọna l'Ekoo

Oríṣun àwòrán, Tokunbo Wahab@X

Ileeṣẹ to n ri si imọtoto ayika ati ipese omi nipinlẹ Eko ti mu eeyan mẹjọ ti wọn fẹsunkan pe wọn kọ ojubọ oriṣa saarin ọna lagbegbe Egbe-Ikọtun.

Kọmiṣọna fun eto ayika ati ipese omi l’Eko, Tokunbo Wahab, lo sọ eyi di mimọ loju opo X rẹ logunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.

Wahab ṣalaye pe niṣe lawọn eeyan naa kọle ooṣa soju ọna ijọba, eyi to lodi sofin.

‘’Ọlọ́kan-ò-jọ̀kan òògùn abẹnugọ̀ngọ̀ la tún bá lọ́wọ́ wọn’’

Kọmiṣọna ọhun tẹsiwaju pe oogun abẹnugọngọ ti ko jọ ara wọn lawọn tun ri gba lọwọ awọn eeyan mẹjọ naa.

‘’Eeyan mẹjọ lọwọ ba fun kikọ ojubọ soju ọna lagbegbe Egbe-Ikotun.

‘’A mu wọn pẹlu oogun abẹnugọngọ oriṣiiriṣii ni, a si ti wo ile ooṣa ti wọn wo naa palẹ.’’

Bẹẹ ni Kọmiṣanna eto ayika l’Ekoo wi.

O fi kun un pe ẹsun mii tun ni ti awọn oogun ti wọn mu wọn pẹlu ẹ yii.

Eyi to jẹ kawọn tete palẹ wọn mọ, ki wọn ma baa fi tiwọn da wahala silẹ saraalu lọrun.