Ìjọba Osun jáwe lọ rọọ́kún nílé fún olùkọ̀ nítorí pé ó sọ̀rọ̀ tako ìjọba lórí Facebook

Philip Akinyemi

Oríṣun àwòrán, Philip Akinyemi/Gboyega Oyetola

Iroyin kan n kaakiri pe ijọba ipinlẹ Ọṣun ti paṣẹ lọ rọọkun nile fun olukọ ileewe girama kan nipinlẹ naa, Ọgbẹni Akinyẹmi Phillip lori awọn agbejade kan to n fi sita loju opo facebook rẹ.

Iroyin ọhun ni ijọba ipinlẹ Osun ti paṣẹ lọ rọọkun nile fun okunrin naa, to jẹ olukọ nile ẹkọ girama Masifa Community Grammar School, to wa ijọba ibilẹ Ejigbo.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ẹṣẹ kan ṣoṣo ti okunrin naa ṣe ni pe o maa n sọrọ, osi tun maa n fi awọn aworan lede loju opo Facebok ni atẹlẹyin fun ẹgbẹ The Osun Pregressives, TOP, eyii to jẹ abala kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC, eyii igbagbọ wa pe wọn jẹ alatako si gomina Gboyega Oyetola to wa lori alefa lọwọlọwọ.

Ṣaaju ni wọn ti kọkọ fun okunrin naa lẹta wa wi tẹnu rẹ lori idi to ṣe n “tabuku” Oyetola loju opo Facebook rẹ.

Lẹta wa wi tẹnu rẹ naa ni “Awọn ọrọ ti o maa fi lede loju opo Facebook fi han pe o ti n ya bara kuro ninu isẹ ti ijọba gba ọ fun gẹgẹ bii olukọ.”

Philip Akinyemi

Oríṣun àwòrán, Philip Akinyemi

“O ti mu ọrọ oṣelu ni okunkundun ju iṣẹ olukọ ti wọn gba ọ fun lọ, nipa ṣiṣe bẹẹ, o ko jẹ olotitọ si ijọba ipinlẹ Osun gẹgẹ bii oṣiṣẹ ijọba.”

“Awọn atẹjade rẹ lori ayelujara jẹ iwa aibọwọ fun ijọba ipinlẹ yii ati gomina to n ṣiṣẹ takun-takun lati san owo oṣu awọn oṣiṣẹ rẹ̀.”

Amọ ṣa, ninu lẹta ti wọn ti ni ko lọ rọọkun nile, ẹṣẹ ti wọn ni o ṣẹ ni pe o ṣi ọọfisi rẹ lo gẹgẹ bii olukọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lẹta naa, ti wọn kọ logunjọ, oṣu kejila, ọdu 2021 yii, ti E.O Onatola buwọlu sọ pe “Wọn ni ki n fi akoko yii sọ fun ọ pe lẹyin ti o ṣi ọọfisi rẹ lo, iwa ti o wu ko dun mọ awọn alaṣẹ ninu.”

“Pe, iwọ ọgbẹni Akinyemi Philip ti o jẹ olukọ nile ẹkọ Masifa Community Grammar School, Ejigbo, gbajumọ ọrọ oṣelu ju iṣẹ olukọ ti ijọba gba ọ fun.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Awọn ọrọ ti o maa n kọ lori itakun ayelujara lodi si ofin to gbe iṣẹ oṣiṣẹ ijọba ro, o ko si ni aṣẹ lati wọ inu ile ẹkọ lai kọkọ gba aṣẹ lati ṣe bẹẹ.”

BBC Yoruba kan si okunrin naa, o si fi idi ọrọ naa mulẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Abẹwo BBC si oju opo Facebook okunrin naa fi han pe ọrọ oṣelu pọ daadaa loju opo rẹ.

Ọpọ awọn eeyan ipinlẹ Osun lo ti bẹrẹ si n bu ẹnu atẹm ijọba ipinlẹ naa lori igbesẹ ọhun, beẹ si ni awọn ọrẹ okunrin naa lori itakun Facebook ti n sọrọ atilẹyin fun un.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ