Ẹ̀yin olùgbé ìlú Eko, ẹ má bẹ̀rù, bílíọ̀nù mẹ́ta ni a ná lórí ọlọ́pàá lọ́dún 2021- Sanwo-Olu

Sanwo Olu

Oríṣun àwòrán, @Sanwo Olu

Ẹ̀yin olùgbé ìlú Eko, ẹ má bẹ̀rù, bílíọ̀nù mẹ́ta ni a ná lórí ọlọ́pàá lọ́dún 2021- Sanwo-Olu

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti ni k’awọn olugbe ipinlẹ Eko ma fòyà lori eto abo lasiko ọdun to n lọ lọwọ ati ọdun 2022 to n bọ lọna.

Gomina Sanwo-Olu ni owo to le ni bílíọ̀nù mẹ́ta naira ni ijọba na lori ileeṣẹ ọlọpaa lodun 2021 ki eto le mọyan lori.

Sanwo-Olu ni ijọba oun n sapa lati ri pe ipinlẹ Eko ni eto abo to peye julọ wa l’ọdun 2022.

Gomina ipinlẹ Eko ijọba yoo tẹsiwaju lati maa ṣe ojuṣe rẹ nípa ipese eto abo ti yoo mu alaafia jọba kaakiri ipinlẹ Eko.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Sanwo-Olu ni ajọ eleto abo igberiko yoo tubọ maa ṣiṣẹ pọ pẹlú ọlọpaa agbegbe lati ṣe iranwọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipa didari ero, igbokegbodo ọkọ at’awọn iṣẹ mii lawujọ.

Ninu ọrọ tiẹ, akọwe agba ajọ LSSTF to n ṣakoso ọrọ owo lori eto abo nipinlẹ Eko, Ọmọwe Abdurrazaq Balogun ṣalaye pe owo perete ni ajọ naa n ri gba eleyi to fa Ifaseyin fun ajọ naa lọdun 2021.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọmọwe Balogun ni banki mẹta lo fun ajọ LSSTF lowo iranwọ lori eto abo.

O ni N1.4bn ni ajọ LSSTF ri gba lọdun 2021 eyi to jẹ pe ọpọ ninu rẹ jẹ ẹjẹ ati awọn ọdun to lọ sẹyin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Alaga ajọ naa, Ọgbẹni Kehinde Durosinmi-Etti ni ajọ LSSTF n kopa ribiribi lati ri pe eto abo to mọyan lori wa nipinlẹ Eko.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ẹwẹ, kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa koju oríṣìíríṣìí ipenija lọdun 2021 pẹlu iwọde EndSARS.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Amọ, Ọgbẹni Odumosu ni ohun to jẹ nkan iwuri ni ko si ikọlu si ile ifowopamọ kankan nipinlẹ Eko lọdun 2021.