Mọ̀ síi nípa Bola Ige tó jẹ́ mínístà ètò ìdájọ́ ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣì ń wá ìdájọ́ òdòdo lórí ikú rẹ̀

Bola Ige

Oríṣun àwòrán, @Onibokun

Lagbo oselu,eto ẹkọ ọgbin ati eto to ni se pẹlu ọrọ ofin ilẹ Naijiria, Bola Ige da bira ti ipa to si ko kii se kekere.

Bola Ige se Gomina ri, O se Kọmisana ri, o se agbẹjọro koda o de ipo to gajulọ nidi eto idajọ nigba to jẹ Kọmisana eto idajọ Naijiria.

Bi a ba ni ka maa tẹnu bọ ọrọ nipa Cicero Esa Oke, ilẹ yoo kun koda o seese ki apilẹkọ yi nikan ma to.

Nitori asiko ati aaye, a o mẹnu ba diẹ ninu ohun to yẹ ka mọ nipa Bola Ige paapa julọ lasiko yi to se pe o pe ogun ọdun ti awọn agbenipa ti da ẹmi Bola Ige legbodo tawọn eeyan si n se idarọ rẹ naa.

James Ajibola Idowu Ige jẹ ọmọ bibi ilu Esa Oke nipinlẹ Osun toni lọjọ Kẹtala osu Kẹsan ọdun1930.

O gbe Kaduna nigba kekere rẹ sugbọon o kuro ni Kaduna lati wa si apa iwọ oorun Guusu Naijiria lẹni ọdun mẹrinla.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nipa ti eto ẹkọ, o ka ẹkọ Girama ni ile ẹkọ Ibadan Grammar School 1943-48 ati ni Fasiti Ibadan.

Lati fasiti Ibadan lo ti tẹsiwaju lọ si University College London to ti kawe gboye imọ ofin ni 1959.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Wo igbe aye Oloye Bola Ige:

O di agbẹjọro ni ọdun 1961.

Nipa ede sisọ Bola Ige le sọ ede Yoruba, Igbo ati Hausa daadaa.

O kọ ọpọ iwe lasiko aye rẹ to si jẹ pe wọn gbe wọn sita pada laipẹ si igba to ku.

Agbẹjọro oloselu

Bi Bola Ige ba n sọrọ ọpọ a maa wo ẹnu rẹ bi igba pe iru ẹda wo leleyi.

Ọrọ da saka lẹnu rẹ ti eleyi si jẹ ki ọpọ fẹran rẹ lagbo oselu ati nidi isẹ agbẹjọro rẹ to yan laayo.

Awọn ọmọ ode isẹnyi le maa mọ riri ki eeyan le sọrọ to mọgbọn wa nitori aikọbi ara si eto ẹkọ sugbọn lasiko Bola Ige, ko fi eto ẹkọ sere rara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Yala nigba to ba awọn Awolowo logba labẹ asia ẹgbẹ oselu UPN tabi nigba ti wọn fi jẹ Kọmiṣọnna eto ọgbin labẹ ijọba ologun Yakubu Gowon to fi mọ ibasepọ rẹ pẹlu ijọba Olusegun Obasanjo, Ige a maa fi ipa rẹ lelẹ nibi eyikeyi isẹ ti wọn ba gbe fun un.

Bola Ige se Minisita feto ọrọ ina mọnamọna sugbọn oun naa ko ribi wa ojutu si ọrọ ipenija aisina to n ba ileesẹ yi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lọdun 2000-2001 Bola Ige di ipo amofin agba Naijiria ti a ko si le gbagbe awọn igbesẹ rẹ lasiko yi.

Ninu wọn la ti gbọ pe o sọ pe ijọba Naijiria fẹ se agbekalẹ ofin Naijiria lọna igbalode soju ayelujara tawọn eeyan yo si maa le wo loju opo ileesẹ eto idajọ ilẹ yi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kini èrò Bola Ige ati igbejọ Sharia ni Naijiria?

Bola Ige tako ninu ọrọ ati ise, idasilẹ ofin Sharia ni apa ariwa Naijiria.

Ni osu Kọkanla, ọdun 2001, o kede pe ijọba apapọ Naijiria ko ni faaye gba ki wọn pa arabirin Safiya Hussaini ti ile ẹjọ Sharia sọ pe ki wọn sọ oko pa nitori pe o se agbere.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bawo ni Bola Ige ṣe ku?

Bola Ige n mura lati gba ipo tun tun gẹgẹ bi ọmọ igbimọ ajọ isọkan agbaye to n risi ọrọ eto ofin United Nations International Law Commission ni awọn olubi seku pa ni ile rẹ to wa ni Ibadan.

Iku Bola Ige waye ni ọjọ Kẹtalelogun, osu Kejila, ọdun 2001 ni awọn agbebọn lọ ka Bola Ige mọ ile rẹ to wa ni Ibadan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Wọn ko bikita pe o jẹ Minisita feto idajọ ti wọn fi pa a.

Saaju ki o to papoda,a wuyewuye laarin ẹgbẹ oselu rẹ: Alliance for Democracy ni ipinlẹ Osun nigba naa ni eyi ti awọn kan lo seese ko fa iku rẹ.

Ija laarin Gomina ipinlẹ Osun nigba naa Bisi Akande ati igbakeji rẹ Iyiola Omisore la gbọ pe o fa iku oloselu kan Odunayo Olagbaju ki Bola Ige to wa ki lẹyin igba naa .

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Iwadii waye lori iku Bola Ige koda wọn wọ igbakeji Gomina Iyiola Omisore lọ sile ẹjọ lori ẹsun pe o lọwọ ninu iku Bola Ige.

Asẹyinwa asẹyinbọ, Iyiola Omisore ati awọn mẹwaa mii ti wọn fẹsun kan gba itusilẹ lọdọ adajọ ti wọn si ni wọn ko mọ nipa iku Bola Ige.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Titi di ba se n sọrọ yi, wọn ko ti ridi ohun tabi awọn eeyan to mọ nipa iku Bola Ige.

Ilu Ibadan ni wọn sin Bola Ige si.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ