Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ń pèsè iná mọ̀nàmọ́ná olówó pọ̀ọ̀kù,wo ọgbọ́n tó dá síi

Adan Hussein Dida

Awọn eeyan ti n gboṣuba kare fun akẹkọọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ kan to fi bio-gas pese ina mọnamọna fawọn ọpọ ibugbe ni agbegbe Boranza ni Ethiopia

Adan Hussein Dida to jẹ akẹkọọ ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ sọ pe oun se irinṣẹ ipese ina yi lati mu idẹkun ba awọn araadugbo ti ko ni ohun amayedẹrun bi ina, ile iwosan ati oju ona.

Ọmọ ọdun mẹrinla nii ṣe.

O ṣalaye pe ẹyinkule ile awọn obi rẹ lo ti bẹrẹ iṣẹ naa to si ni oun lo igbẹ ẹranko lati inu koto kan toun gbẹ.

Lati ibẹ o ni oun ribi seto ina mọnamọna fawọn ile ibugbe mẹjọ.O si ni ki ile kọọkan maa san $0.87 loṣooṣu lowo ina.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awọn araadugbo ibi to ti se eto yi maa n sin nkan ọsin ṣugbọn plu bi ipenija aisi omi ṣe ba wọn, ọpọ ni ko rọwọ fi họri ti iṣẹ si n daamu wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Adan ati ẹbi rẹ n lo owo ti wọn ba ri nibi ipese ina mọnamọna yi lati fi gbọ bukata wọn.

O ni ”Inu mi dun si ohun ti mo ri ṣe nitori wọn ni mo din awn ni inawo batiri ati tọọṣi ku.Awọn ọmọ wn n ri iwe ka nile dipo ki wọn duro di ọjọ keji lati ṣe iṣẹ amurele wọn”

Awọn akẹkọọ ile ẹkọ Tula Web School

Olukọ rẹ, Boru Sora s pe Adan n tẹsiwaju pẹlu irinṣẹ rẹ toun ti pe ipenija oju ọna ti ko da n di lọwọ lati lọ ra eelo ti yoo nilo.

Arakunrin Boru ni ”Ọlọpọlọpọ pipe ọmọ ni Adan jẹ.Yatọ si irinṣẹ biogas to ṣe,o tun ti n tun redio ati awọn irinṣẹ mii ṣe lati fi pese baalu to le fo niwọn ọgọrun mita”.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awọn akẹkọọ mi ni ile ẹkọ Adnan ti n ri Adan gẹgẹ bi awokọṣe ti awọn naa si ti n mura si ṣiṣe irinṣẹ ti wọn naa.

Afojusun ati ireti rẹ ni lati kọ ẹkọ imọ ẹrọ ni fasiti Borana tuntun ti wọn da silẹ ni Yebelo

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ