Àwọn àǹfààní tí Zobo le ṣe fún ara rẹ, àti ipa tó le ni lára aláboyún

Aworan zobo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ènìyàn kan tó gbajúmọ̀ lórí ayélujára ló gbé fọ́nrán kan jáde pé òun kò tún báwọn mu zobo mọ́ nínú oyún.

Ó ní ìdí ni pé òun mu zobo nínú oyún tó sì fa kí ọmọ máa mú òun kalẹ̀ nígbà tí ọmọ kò ì tíì tó bí.

Èyí ló mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn máa sọ ìrírí wọn nígbà tí wọ́n mu zobo nínú oyún àti ohun tó ṣe lára wọn.

Ẹni tó gbé fídíò náà jáde ṣàlàyé pé òun kò gbàgbọ́ pé zobo máa ń fa kí oyún wálẹ̀ lára ènìyàn tẹ́lẹ̀, tí òun sì rò pé àhesọ lásán ni àmọ́ ó jọ pé òótọ́ ni pé zobo máa ń ṣe àwọn nǹkan náà.

Ó ní òun ti gbọ̀gbọ́ pé lóòótọ́ ló máa ń fa kí oyún wálẹ̀ lára obìnrin.

Ó ní nígbà tí oyún òun wà ní oṣù mẹ́rin ni òun kọ́kọ́ mú zobo nínú oyún, ó ní kò pẹ́ tí òun mu zobo náà ni inú bẹ̀rẹ̀ sí ní run òun àmọ́ òun kò kà á sí rárá pé zobo tí òun mu ló fà á.

Ó fi kun pé àwọn ará ilé wá ṣèkìlọ̀ fún òun láti má mu zobo mọ́ nítorí ó máa ń ba oyún jẹ́ àmọ́ tó ní zobo ló máa ń wu òun mu nínú oyún.

Lẹ́yìn tó gbé fídíò náà jáde ni ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin jáde láti sọ̀rọ̀ nípa ìrírí wọn, tó sì fa awuyewuye lórí ayélujára.

Èyí ló mú kí BBC ṣe ìwádìí lórí ohun mímu yìí nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn ló fẹ́ràn rẹ̀ látara àwọn àǹfàní púpọ̀ tó ní fún ìlera ènìyàn pàápàá obìnrin.

Zobo jẹ́ ohun mínu tó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfàní fún obìnrin lásìkò tí wọ́n bá ń ṣe nǹkan oṣù lọ́wọ́ àti lẹ́yìn tí wọn kò bá ṣe nǹkan oṣù mọ́ rárá.

Ó máa ń ṣe ẹ̀dọ̀, àti àwọn ẹ̀yà ará mìíràn ní àǹfàní, tó sì máa ń dènà irun jíjá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àjọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan, National Library of Medicine ní zobo dára púpọ̀ fún àgọ́ ara tí ènìyàn bá mú un ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì.

Àwọn àǹfàní wo ni zobo máa ń ṣe fún ara?

Ewé zobo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Onímọ̀ nípa oúnjẹ kan, Onoja Deborah sọ fún BBC pé àwọn èròjà tó dára, tó sì máa ń ṣe ara lóore tó pọ̀ gan.

Onoja ní àwọn èròjà bíi flavonoids àti anthocyanins tí wọ́n máa ń mú àìsàn ọkàn àti ààrùn jẹjẹrẹ jìnà sí ènìyàn.

Dókítà Olowofoyeku náà sọ pé àwọ̀ zobo ìyẹn àwọ̀ pupa rẹ̀ ní àǹfàní tó máa ń mú bá ara.

Bákan náà ló ní iṣẹ́ tí zobo máa ń ṣe tako oyún ìju àti pé ó máa ń pèsè ẹ̀jẹ̀ fún ara.

Àmójútó ara sísan

Ó ṣàlàyé pé zobo dára fún ẹni tó bá fẹ́ mójútó ara sísan rẹ̀ nítorí zobo kìí jẹ́ kí èèyàn tóbi rárá.

Ó fi kun pé zobo ní bí ó ṣe máa ń ní ipa lórí amylase enzyme èyí tó máa ń mú àdínkù bá bí ẹ̀yà ara ṣe máa ń gba àwọn oúnjẹ tó máa ń fúnni lágbára.

Ó ní èyí sì lè mójútó bí èèyàn ṣe lè tóbi tó.

Ẹ̀jẹ̀ ríru

Onoja ní ìwádìí ti fi hàn pé èròjà anthocyamins máa ń ṣe àmójútó bí ẹ̀jẹ̀ ṣe ń rìn lára tó sì máa ń mú àdínkù bá ẹ̀jẹ̀ ríru.

Bẹ́ẹ̀ náà ló ní zobo ní àwọn èròjà tó máa ń mójútó bí èèyàn ṣe máa ń tọ̀.

Tí Dókítà Abosede sì sọ pé ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé bí èèyàn bá ṣe ń tọ̀ ni yóò máa tọ sodium tó máa ń fa ẹ̀jẹ̀ ríru kúrò lára.

Àmójútó àìsàn jẹjẹrẹ

Dókítà Abosede tún ṣàlàyé pé zobo dára láti fi ṣètọ́jú àwọn àìsàn jẹjẹrẹ kan.

Ó sọ pé ó ní bí ènìyàn ṣe lè se zobo tó lè fi mú ìwòsàn bá ẹni tó bá ní àìsàn jẹjẹrẹ.

Àmọ́ ó ní bí wọ́n ṣe máa ń pèèlò zobo fún ìtọ́jú àìsàn jẹjẹrẹ yàtọ́ sí èyí tí àwọn èèyàn máa ń mú gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìndòdò.

“Dípò omi tí àwọn máa ń lò láti fi se zobo, ọ̀tọ̀ ni nǹkan tí wọ́n máa ń lò láti fi se zobo tí wọ́n máa ń lò láti fi wo àìsàn jẹjẹrẹ.

Kí ni àwọn onímọ̀ ìlera sọ nípa mímu zobo nínú oyún?

Dókítà Abosede Olowofoyeku tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé nínú ìmọ̀ “Drug Discovery and Development From Nature” oríṣiríṣi ọ̀nà ni wọ́n máa ń gbà pèlò ewé zobo kí ó tó di mímu àti pé ọ̀nà tí wọ́n bá gbà pèèlò rẹ̀ ni yóò sọ irú iṣẹ́ tí yóò ṣe lára.

Lára àwọn ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà pèèlò rẹ̀ ni síse ewé zobo fún ó kéré tán wàkátì kan kó tó di mímu.

Ọ̀nà mìíràn tí wọ́n máa ń gbà sè é ni dída ewé náà sínú omi tó bá gbóná, tí wọn yóò sì yọ tó bá ti toró tán.

Ọ̀nà kẹta ni dída ewé zobo sínú omi tútù fún ọjọ́ mẹ́ta kí wọ́n tó yọ omi rẹ̀.

Dókítà Olowofoyeku ní tó bá jẹ́ ọ̀nà kẹta ni aláboyún bá lò láti fi pèèlò zobo kí ó tó mu ún, ó ṣeéṣe kí oyún náà wálẹ̀.

Ó ṣàlàyé pé ọ̀nà pípéèlò zobo nípa síse ewé zobo fún wákàtí ó kéré tán kí èèyàn tó mu ún ni ọ̀nà tó dára jùlọ láti pèèlò rẹ̀ fún aláboyún.

Ó ní gbogbo ọ̀nà mẹ́ta yìí ló ní iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan tí wan máa ń ṣe lára.

Ó fi kun pé nínú àwọn èròjà aṣaralóore tó wà nínú zobo tó máa ń mú kí oyún wálẹ̀ jẹ́ èyí tí kò rí ara gba iná rárá.

“Ìdí nìyí tó fi jẹ́ pé iṣẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló máa ṣe nígbà tí ẹ bá fi omi gbígbóná tàbí omi tútù sè é.”

Bákan náà ló tún tẹ̀síwájú pineapple tí ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ń lò láti fi ṣe adùn fún zobo náà ní èròjà tó lè ba oyún mọ́ èèyàn lára pàápàá inú rẹ̀ gangan.

“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń lo pineapple láti fi ṣe àdùn fún zobo wọn, àmọ́ jíjẹ inú pineapple kò dára fún ẹni tọ bá lóyún.

“Inú pineapple ní èròjà tó ń jẹ́ “bromelain” tó máa ń fa kí ọmọ mú aláboyún láìpá ọjọ́.

Dókítà náà ṣàlàyé pé ọ̀nà tó dára láti se zobo fún aláboyún tó bá fẹ́ lo pineapple ni láti yọ inú rẹ̀ dànù kí wọ́n sì se ara rẹ̀ jiná dáadáa nítorí bromelain máa ń wà lára rẹ̀ náà.

Kí ni àwọn ìpalára tí zobo máa ń mú bá èèyàn?

Dókítà Abosede Olowofoyeku

Oríṣun àwòrán, ABOSEDE OLOWOFOYEKU

Onímọ̀ oúnjẹ Onoja ni bí zobo ṣe da lára, tó sì ní àwọn àǹfàní tó ps tó ń ṣe fún àgọ́ ara náà ló ní àwọn ìpalára tó lè mú bá èèyàn tí ó bá pọ̀ lápọ̀jù.

Lára àwọn ìpalára tí wọ́n ní ó lè fà ni iní rírun, kí ìfúnpá èèyàn lọlẹ̀ ju bí ó ṣe yẹ lọ àti pé ó lè mú àyípadà bá ipá oògùn tí èèyàn bá ń lògùn lọ́wọ́.

Onoja ní zobo lè fa kí ìfúnpá èèyàn lọlẹ̀ púps tí èèyàn bá ń mu zobo pupọ̀ àti pé kò da fún ẹni tó bá máa ń ní ẹ̀jẹ̀ ríru láti máa mú pẹ̀lú àwọn oògùn tí wọ́n bá fún.

Bákan náà ni dókítà Abosede ní zobo le fa kí èèyàn máa yàgbẹ́ gbuuru tí àwọn èròjà tí wan bá fi pèèlò rẹ̀ bá lè fà á.

Ó wòye pé kìí ṣe zobo fúnra rẹ̀ ló máa ń mú èèyàn yàgbẹ́ bíkòṣe àwọn nǹkan tí wan máa ń sèpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.