Ènìyàn tó kú níbi ìjàmbá iná ní Amẹ́ríkà wọ 106

Àwọn nǹkan tí iná náà jó kù

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orúkọ ènìyàn méjì nínú àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná tó wáyé ní Hawaii ni wọ́n ti kéde rẹ̀ báyìí lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan tí àwọn ènìyàn 106 pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàmbá náà.

Robert Dyckman, ẹni ọdún 74 àti Buddy Jantos ẹni ọdún 79 ni wọ́n ti dárúkọ wọn báyìí.

Àwọn mẹ́ta mìíràn ni wọ́n tún ti mọ orúkọ wọn àmọ́ tí wọ́n ń dúró láti sọ fún àwọn ẹbí wọn kí wọ́n tó gbé àwọn orúkọ náà síta.

Ìjàmbá iná ọ̀hún tó ba gbogbo ìlú Lahaina jẹ́ láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí ni wọ́n ti ń wá àwọn ènìyàn tó bá ìjàmbá ọ̀hún lọ.

Iléeṣẹ́ ìròyìn New York Times ní ilé ìgbé àwọn arúgbó ni wọ́n ti rí òkú Jantoc.

Ìyàwò ọmọ Jantoc ní ó ń ṣe òun bí ẹni pé bàbá náà kò ì tíì kú, “ó ń ṣe mí bíi wí pé ó kàn sùn ni.”

Àwọn ajá òyìnbó ogun tí wọ́n ti kọ́ ní ẹ̀kọ́ bí wọ́n ṣe máa ń gbọ́ òórùn ibi tí òkú ènìyàn bá wà ni wọ́n ti fi ń wá òkú àwọn ènìyàn ní ojúlé sí ojúlé lẹ́yìn ìjàmbá iná náà.

Àwọn ènìyàn tí nǹkan ìní wọn jó

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gómìnà Josh Green ní ìdá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ibi tí ìjàmbá iná náà ti wáyé ni wọ́n ti ṣe àyẹ̀wò rẹ̀ ní ìrọ́lẹ̀ ọjọ́ Ìṣẹ́gun tó sì ní ó ṣeéṣe kí àwọn ènìyàn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ pọ̀ ju iye tí wọ́n fi síta tẹ́lẹ̀ lọ.

Àwọn òṣìṣẹ́ gbọ́dọ̀ parí iṣẹ́ wọn láti mọ́ àwọn tó kú, èyí tí wọ́n máa ṣe nípasẹ̀ ṣíṣe àyẹ̀wò òkú wọn.

Ààrẹ Amẹ́ríkà, Joe Biden àti ìyàwó rẹ̀ Jill Biden yóò ṣe ìrìnàjò lọ sí Hawaii lọ́jọ́ Ajé gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde kan láti ilé iṣẹ́ ààrẹ ṣe sọ.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè bí ààrẹ Biden kò ṣe tíì yọjú sí Maui, ibi tí ìjàmbá náà ti ń wáyé ló ń bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ìlú nínú, tí wọ́n sì fi èyí hàn nígbà tí wan ń bá BBC sọ̀rọ̀.

Biden ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní ìdí tí òun kò ì tíì yọjú síbẹ̀ ni pé lílọ síbẹ̀ òun máa dí ètò ìrànwọ́ tó ń lọ níbẹ̀ lọ́wọ́ nítorí ó dá òun lójú pé lílọ síbẹ̀ òun máa dí ètò náà lọ́wọ́.

Àjọ tó ń mójútọ ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní Maui ní ó máa ná àwọn tó 45.52bn láti fi tún àwọn nǹkan tí iná náà bàjẹ́ kọ́ àti pé ó máa pẹ́ láti láti lè ṣe àkójọ iye nǹkan tó bá iná náà lọ.

Ará Maui kan, Koa Kekahuna sọ fún BBC pé ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ gan ni kò fẹ́ padà sẹ́nu iṣẹ́ wọn nítorí bí nǹkan ṣe bàjẹ́ tó.

Olùgbé ibẹ̀ kan, Les Munn ní òun ti rí $500 lọ́wọ́ àjọ tọ ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ti ìjọba àpapọ̀ ní iye tí kò tó iye tí wọ́n ń gba yàrá ní ilé ìtura ní agbègbè náà.

Ní Lahaina, tó jẹ́ olú ìlú Hawaii, níṣe ni àwọn ènìyàn ń gbọ́kànlé àwọn ohun ìdẹ̀kùn tí àwọn olùgbé Maui ń pèsè fún wọn.

Ní ọjọ́rú ni wọn yóò ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí afárá Honoapiilani fún ìgbà àkọ́kọ́, tó jẹ́ ọ̀nà tó wọ Lahaina, fún àwọn tí wọn kìí ṣe olùgbé ìlú náà.

Láti ọjọ́ Ìṣẹ́gun tó kọjá ni ọ̀nà náà ti wà ní títìpa, tí wọ́n yóò sì máa ṣi fún gbogbo ènìyàn lójú ọ̀sán báyìí.

Àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ àtàwọn ọmọ ìlú nìkan ni yóò le wọ ibẹ̀ ní alẹ́.

Ó kéré tán, ènìyàn 93 ti kú nínú ìjámbá iná tó sọ ní ilẹ́ Amẹrika

Aworan

O kere tan eniyan 93 lo ti gbẹmi mi lẹyin ti ina sọ ni agbegbe Maui, ni ilu Lahaina, lorilẹede Amẹrika.

Ina nla to sọ lati papa ni wọn ti ṣapejuwe gẹgẹ bi eleyii to lagbara ju ni itan orilẹede Amẹrika.

Nibayii ti wọn ṣi n gbiyanju lati mọ iye awọn eniyan to ku, gomina ipinlẹ Hawaii ni o ṣeeṣe ki iye awọn eniyan to ti ku ju bẹẹ lọ.

Bakan naa ni wọn ṣi n wa ọgọgọrun awọn eniyan to wa nibi iṣẹlẹ ijamba ina naa.

Bẹẹ si ni awọn miran fi ile ati ọna wọn silẹ lati sa asala fun ẹmi wọn.

Ninu ọrọ rẹ, gomina Hawaii, Josh Green ni ijamba to kọja afẹnusọ ni iṣẹlẹ naa ti o ni awọn ara ipinlẹ Hawaii n koju lọwọ.

Nibayii, gomina naa ni igbiyanju n lọ lọwọ lati pese eto ilera ati ile igbe fun awọn to jajabọ ninu iṣẹlẹ naa.

Bakan naa ni igbiyanju nlọ lọwọ lati wa awọn mọlẹbi to ṣọnu lasiko ti wọn n sa asala fun ẹmi wọn.

Aworan