Ọ̀jọ̀gbọ́n Akintoye ṣàgbékalẹ̀ ”App” PAJAWIRI tí yóò máa tú àṣírí àwọn ajínigbé àti ọ̀daràn

Ọjọgbọn Banji Akintoye

Oríṣun àwòrán, Ilana Omo oodua

Adari ẹgbẹ Ilana Omo Oodua to n ja fun idasilẹ orilẹede iran Yoruba, Ọjọgbọn Banji Akintoye ti ṣe agbekalẹ aapuu alagbeka kan ti o pe orukọ rẹ ni ”PAJAWIRI” eyi ti yoo maa tu aṣiri awọn ajinigbe.

Aapuu PAJAWIRI yii to jẹ alagbeka le sọ ibi ti awọn ajinigbe gbe awọn eeyan ti wọn ji gbe lọ.

Bakan naa, aapuu PAJAWIRI le fun eeyan lara nipa ewu to le ṣẹlẹ lagbegbe ati ayika ti ẹni naa ba wa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọjọgbọn Akintoye ni Yoruba yoo lo ọpọlọ ti Eleduwa fun wọn lati ja fun idasilẹ Yoruba yapa kuro lara Naijiria.

O ni aapu PAJAWIRI yii yoo sọ ibi ti awọn ọdaran ajinigbe ba ko awọn ti wọn jigbe pamọ si niwọn igba ti o ba ti wa lọwọ ẹni ti wọn ji gbe bo ya o wa ni pipa tabi titan.

Bakan naa ni aapuu yii tun ni nkan ti wọn n pe ni AFINIHAN tawọn eeyan ti wọn ko ba n lo foonu android le lo.

Nigba ti o n sọrọ nibi ayẹyẹ ifilọlẹ aapuu ọhun niluu Ibadan, Ọjọgbọn Akintoye to sọrọ lori ẹrọ igbọrọkaye ṣalaye pe agbekalẹ aapuu PAJAWIRI fihan pe iran Yoruba ni ọpọlọ pipe ju ki ẹnikan maa jẹ gaba le wọn lori lọ.

”A ti fihan fun gbogbo araye pe iran Yoruba kii ṣe iran kan ti ẹnikẹni le ko lẹru.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awọn ọgbọn inu ati lilo ọpọlọ ti Eleduwa fi jinki wa naa ni a maa lo lati gba ara wa kuro ninu ajaga orilẹede Naijiria.

Ẹnikẹni ti aapuu PAJAWIRI ba wa lọwọ rẹ le tan an lẹsẹkẹsẹ nibi kibi ti ewu ba wa.

Nipa bayii, wọn o lanfaani lati jẹ ki awọn ẹbi wọn mọ ohun ti o n ṣẹlẹ si wọn nibi ti wọn wa.

Ko si ọmọ Yoruba to yẹ ki o da wa yala ninu oko, ile ẹkọ, ọja, ṣọọbu tabi nibi kibi lai ni aapuu yii lọwọ.

Awọn onimọ ẹrọ wa nilẹ Yoruba ni wọn lo ọpọlọ ti Eleduwa fun wọn lati ṣe agbekalẹ aapuu iyebiye yii fun iwulo gbogbo wa nilẹ Yoruba,” Ọjọgbọn Akintoye ṣalaye.