Ẹ wo ohun tí Ooni yóò ṣe fáwọn olóṣèlú bó se wọ ìpèbí lọ fọ́dún Ọlọ́jọ́

Ooni Adeyeye Ogunwusi

Oríṣun àwòrán, Ooni of Ife Facebook

Gẹgẹ bi ara igbesẹ fun ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ ti Ọdun yii, Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Enitan Ogunwusi, Ọjaja keji ti wọ ipebi lọ lọjọ Aiku, nibi ti yoo wa fun ọjọ meje.

Itumọ ọdun ọlọjọ ni ọjọ ti ọjọ kọkọ bẹrẹ si ni jẹ ọjọ. Iyẹn ni pe ọjọ ti ojumọ kọkọ mọ lorilẹ aye.

Ninu iṣẹṣe ilu Ile Ifẹ, ọdun ọlọjọ ni wọn ya sọtọ lati ṣe ayajọ ọjọ ti Olodumare kọkọ da ile aye.

Ninu ọrọ rẹ ki o to wọ inu ipebi lọ Ọọni Ogunwusi ni ko si ohun meji ti oun nilo lati ṣe ninu ipebi ọlọjọ meje naa ju gbigba adura fun idagbasoke orilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Olori ọba alade naa ni bi awọn ọmọ Naijiria ba woye daadaa, ọpẹ lo yẹ Naijiria paapaa pẹlu ajakalẹ arun COVID-19 to gbode lagbaye ṣugbọn ti ọṣẹ rẹ ṣu n mọ niwọnba ni Naijiria.

O ni sibẹ awọn adari ko gbọdọ sinmi lati rii pe ignayegbadun awọn araalu jẹ wọn logun. Ọọni Ogunwusi fi kun un pe idi gan niyi ti oun yoo fi lo ọjọ kẹfa ninu ipebi lati gbadura fawọn aṣiwaju ni Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Wiwọ ipebi ṣaaju ọdun ọlọjọ ṣe pataki pupọ, idi si niyi ti mi o le fi ṣere rara nitori ajogunba lọwọ awọn baba nka mi lati ẹgbẹkẹgbẹ ọdun sẹyin ni.”

Bakan naa lo fi kun pe oun yoo lo asiko naa lati gbadura si Eledumare ko fọwọ tọ awọn oloṣelu lọkan ki wọn lee dẹkun fifi aye araalu ta keke, ki wọn si lee maa tẹti si awon ohun gbogbo to n dun araalu lọkan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ