Fídíò, Ọ̀pẹ́lọpọ́ Gómìnà Seyi Makinde lára mi, ẹbí tó yẹ kó ràn mí lọ́wọ́ ní mo lówó míò fi mọ ẹbí – Ridwan-Scorpion Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò, Duration 8,57

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Scorpion ti di gbajugbaja abẹṣẹkubiojo pẹlu ami ẹyẹ kan to tun ṣẹṣẹ gba gẹgẹ bi ajawe olubori agbaye fun International Super Featherwight Champion.

Ridwan Oyekola ni orukọ rẹ amọ ọpọlọpọ mọ ọ si “Scorpion”. O ni ki okiki to de fun oun gan ni awọn eeyan ti n pe oun ni olowo to si jẹ pe oun ko tii jẹ nkankan asan okiki orukọ loun kan ni.

Ridwan-Scorpion boxer

O ṣalaye pe ko si ni to n ṣe iru iṣẹ yii ninu idile oun amọ ẹgbin kan ti oun koju lo jẹ ki oun bẹrẹ ẹṣẹ jija tori o pade obinrin kan to fẹ baa ja lai mọ pe ogbontarigi abẹṣẹkubiojo gan ni obinrin hun to si luu bii bara.

“Mo ti gba sọwedowo miliọnu mẹwaa ri to jẹ pe kinkini ninu rẹ lo pada tẹ mi lọwọ”.

Ridwan ni ẹbun owo miliọnu mẹwaa ti oun ri gba lọwọ Gomina ipinlẹ Oyo lo gbe oun jade gẹgẹ bi ilumọọka.

“Tori eyi, lai tilẹ tii gba owo, awọn ẹbi ati ọrẹ ti n ro pe mo ti di olowo ti wọn si n sọ pe mo lowo mi o fi ran awọn lọwọ.

Ridwan-Scorpion boxer ati Seyi Makinde

Mi o ni ọkọ ayọkẹlẹ ara mi ti mo fi n rin koda mi o ni N100,000 ni asuwọn owo mi, ọla Ọlọrun ati Gomina Seyi Makinde nikan ni mo n jẹ”.

Ridwan ni ẹ́un ọkọ ti wọn ṣeleri gan ko tii tẹ oun lọwọ koda o ni awọn adigunjale tun da oun lọna tori ikede miliọnu mẹwa naira ti oun jẹ.

Sorpion Ridwan kẹnu bọ ọrọ lori bi didi eeyan olokiki ṣe ko ijiya baa.

Ridwan-Scorpion boxer
Ridwan-Scorpion boxer