‘Kàǹkàn ìbílẹ̀, òògùn, àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti fóònù lá bá lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú obìnrin tí wọ́n dédé jù sí àdúgbò wa l’Akure’

Oku obinrin ti wọn ba nilẹ

Iroyin to n tẹ wa lọwọ lọwọ lati ilu Akure ni pe wọn dede ba oku arabinrin kan ti ẹnikẹni ko mọ orukọ rẹ tabi ẹbi rẹ nilẹ lagbegbe ile ijọsin Redeem ati CAC to wa ni Oke-Temidire, Oke-Ijebu.

Awọn ara adugbo ibẹ n sọ pe boya àwọn afurasí ọmọ Yahoo lo wa ju òkú arábìnrin naa sibẹ ṣugbọn a o le fidi eyi mulẹ.

Pasitọ ọkan lara awọn ijọ to wa lẹgbẹ ibi ti wọn gbe oku naa si Pasitọ Peter Adeola lati CAC Oke Idande ba BBC Yoruba sọrọ pe nigba ti awọn ri oku naa, awọn lọ si agọ Ọlọpaa Ijapo lati fi to wọn leti.

Oku obinrin ti wọn ba nilẹ
Oku obinrin ti wọn ba nilẹ

“Ni aarọ yii awọn eeyan wa nibẹ wọn su jọ, mo bere mo sunmọ bẹ mo wa rii pe oku lo wa nibẹ, awa igbimọ ijọ lọ si Agọ Ọlọpaa wọn si ti wa woo, awọn lo da aṣọ boo”.

Pasitọ naa ni ẹya ara rẹ ṣi wa nibẹ nigba ti wọn woo lodi si ohun ti awọn ọdọ to wa nibẹ sọ pe wọn ti baba fa gbogbo abẹ rẹ tori ko sẹni to lee fi aridaju eyi naa han.

O ni awọn Ọlọpaa ti wa ṣe ayẹwo rẹ wọn si da aṣọ boo sibẹ.

Oku obinrin ti wọn ba nilẹ

Lara awọn ti akọroyin BBC ba sọrọ ṣalaye pe lati nkan bii ago meje owurọ oni, ọjọ Iṣẹgun ni awọn ti ba oku rẹ nilẹ.

Oku obinrin ti wọn ba nilẹ

“Baa ṣe rii o ya wa lẹnu keeyan kan dede ba ọmọ eeyan nilẹ”.

Lara awọn nkan ti wọn ba ninu baagi ọra to wa lẹgbẹ rẹ ni kainkain ibilẹ, oogun oyinbo, awọtẹlẹ obinrin, foonu ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oku obinrin ti wọn ba nilẹ

Ẹlomiran ṣalaye pe awọn ti pe awọn Ọlọpaa ki wọn wa gbe oku rẹ toripe o ti di oku ijọba bayii.

Ẹni to ṣoju rẹ koro nigba ti ero pe nibẹ sọ pe lati owurọ ni oku rẹ ti wa nibẹ ti ko si si ẹnikẹni to wa gbee tabi sọ pe awọn mọọ ri.

Ṣe ni èrò kún fọ́fọ́ si ibi ti oku arabinrin naa ṣi wa ni nkan bii ago mejila ku diẹ lasiko ti a n ko iroyin yii jọ ti akọroyin wa lọ foju ganni iṣẹlẹ naa.

Gẹgẹ bi wọn ṣe fi to BBC leti, eyi ni igba akọkọ ti iru nkan bẹẹ yoo ṣẹlẹ ni adugbo wọn.

Oku obinrin ti wọn ba nilẹ
Oku obinrin ti wọn ba nilẹ