Fídíò, Láì lo Kakulétọ̀, mo ní ọpọlọ ìṣirò, tábìlì ìṣirò wà lórí mi – Human Calculator, Duration 3,01

Human Calculator: N kò lo idán àbí àlùpàyídà fún ìṣirò ọpọlọ tí mò ń ṣe

Imọ isiro jẹ ohun ti ko wọpọ, o si maa n le fun ọpọ akẹkọ lati mọ, eyi to n mu ki wọn maa gbe ẹrọ isiro, taa mọ si Calculator kiri.

Amọ eyi ko ri bẹẹ fun akanda ẹda kan, Jolaade Tella, tii se ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ti ọba oke fi imọ isiro da lọla.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Jolaade ni kakuletọ to jẹ eeyan (Human Calculator) ni wọn maa n pe oun, oun lee pin, yọ kuro tabi sọ di pupọ nisẹju aaya.