Fídíò, Èmi kọ́ ló gbé orin ọdún ń lọ sópin kalẹ̀, CAC ló ni í ni mó n ṣe àkójọ orin- Fasoyin, Duration 8,23

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Deborah Adebola Fasoyin: A ti yí orin ọdún ń lọ sópin sí èdè Igbo àti Hausa – Mama Fasoyin

Orin ọdun n lọ sopin jẹ eyi to gbajumọ laarin ọpọ eeyan lai fi ti ẹsin se nitori ọpọ adura to pọ ninu orin naa.

Ti ọdun ba si ti n lọ sopin ni orin naa maa n gbalẹ kan , eyi tawọn eeyan n lo lati se adura funra wọn.

Ọna lati mọ nipa bi agbekalẹ orin naa se waye, lo mu ki BBC Yoruba kan si asaaju ẹgbẹ akọrin obinrin ninu ijọ CAC to kọ orin naa, Mama Deborah Adebola Fasoyin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ, ìya Fasoyin sàlàyé pé àgbáríjọ àwọn akọrin CAC ló jọ máa wọ inú àwẹ̀ àti àdúra láti ṣe àkójọ orin gbogbo orin wọn.

Ìyá Fasoyin sàlàyé pé lẹ́yin àdúra àti àwẹ́ ní wọn yóò wá mú àwọn ti ẹmi mímọ bá fí sí wọ́n lakan láti gbé síta.

O wa fidi rẹ mulẹ pe ọjọ Kọkandinlogun osu Kẹsan ọdun 2020 yii ni wọn ṣe orin náà si ẹ̀yà Igbo àti Hausa fún ànfàni àwọn ti kò gbọ́ Yorùbá.