Ta ni Ashley Folasade Adegoke ti ayé ń pariwo pé òun ni Olorì tó máa rọ́pò Naomi Silekunola?

Ashley

Oríṣun àwòrán, @Ashleyadegoke

Iya Tadenikawo sọrọ ilẹ kun lori ohun ti oju rẹ n ri laafin Oba Adeyeye Ogunwusi ni Ile Ife laarin ọdun mẹta ti wọn fi ṣe igbeyawo gẹgẹ bii tọkọtaya.

Leyin eyi ni iroyin jade lori ayelujara pe arabinrin kan ti wọn pe ni Ashley Folasade Adegoke ni kabiesi fẹ fi rọpo Olori Naomi laafin.

Ọpọ ni bi Naomi ṣe n bọ sita naa ni Ashley a ko wọle ki aafin ma baa gbofo.

Saaju ni Ashley Adegoke to jẹ alakoso ileeṣẹ ti kii ṣe tijọba Ashley Adegoke Foundation ti ki Oba Oonirisa lasiko to n ṣe ọdun mẹfa lori apere awọn Baba rẹ lọna ara ọtọ.

Nibi to ti n ki Ooni ku oriire lo ti ki Kabiesi pẹlu awọn oriki to kọja bẹẹ.

Omo Ajinaja Ogun. Akande Mii Ajiwe Fun’Osha, Okirikiribiti, Dagunduro Oko ODU… Iti Omo Irumole, Ekun ton fin tori tori, Ekun ton fin tiru tiru, Adigimala awo funfun

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ta ni Ashley Adegoke?

Ashley Adekgoke jẹ ọmọ bibi ilu Ile Ife ni ipinlẹ Osun nibi ti ojumọ ti n mọ waye.

Apeje oruko re ni Ashley Folasade Folakemi Adegoke.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O wa lati ile ọla ti wọn ti n jọba ti wọn pe ni Lafogidan ni agboole Adeagba ni Ile Ife

Ashley jẹ Akọṣẹmọṣẹ isiro owo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ilu Oba United Kingdom lo gbe fun ọpọlọpọ ọdun.

Oun ni alakoso ileeṣẹ alaanu Ashley Adegoke Foundation.

Folasade maa n saaba pe ara rẹ ni Aya Oosha.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ