“Epo ló tán nínú bàálù tó já ní Opebi l’Eko”

oko ofurufu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbogbo eeyan to wa ninu baalu ọhun, 5N-VQW lo ba iṣẹlẹ naa lọ.

Ajọ AIB to n maa ṣe iwadii lori iṣẹlẹ ijamba ọkọ ofurufu, Accident Investigation Bureau of Nigeria ti Kede pe epo lo tan ninu baalu hẹlikopita to ja lulẹ lagbegbe Opebi niluu Eko ni guusu iwo oorun Naijiria loṣu kẹjọ ọdún 2020.

Ajọ AIB ni awakọ baalu naa si fẹ fi agidi de ibi to n lọ lẹyin to ri pe epo ti fẹ tan ninu baalu naa.

Kọmiṣọnna ajọ AIB-N, Akin Olateru ni “epo diẹ loku ninu baalu, eyi lo si jẹ ki baalu ọhun lọọlẹ lai le sare mọ.

Bakan naa ni awakọ baalu yii tẹsiwaju lati de ibi to ti fẹ balẹ dipo ko wa ibi to le ba si ni kiakia.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kini abajade igbimo naa so pe o ṣélé?

Abajade igbimọ AIB tun sọ pe ileeṣẹ Quorum Aviation ltd naa kopa ninu ijamba ọkọ ofurufu naa.

Ajọ AIB ni ileeṣẹ Quorum Aviation kuna lati ṣe amojuto baalu wọn daadaa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ajọ naa wa rọ NCAA to n ri sí ọrọ ọkọ ofurufu lati maa ri pe awọn ileeṣẹ ọkọ ofurufu gbọdọ fi eto wọn lori ọrọ abo han lati le dẹkun iru ijamba bayii.

O ni ileeṣẹ Quorum Aviation gbọdọ ri pe awọn oṣiṣẹ wọn mọ ojuṣe wọn ki wọn si maa ṣe daadaa.

oko ofurufu

Oríṣun àwòrán, Getty Images