Ṣé lóòtọ́ ní Ukraine faramọ́ ìhùwàsí ìjọba Nazi tí Hitler kó sòdí nígbà náà?

Ile ti ado oloro Russia ba ni Ukraine

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi orilẹede Russia ṣe n ṣe girigiri kọju ogun lọ si aala rẹ pẹlu Ukraine bayii, bakan naa lo n gbiyanju lati yi oju awọn akọroyin si awijare rẹ – Amọṣa ewo ninu rẹ lo n ṣi araalu lọna?

A ti ṣe agbeyẹwo diẹ lara awọn ọna ti awọn ileeṣẹ iroyin to rọgbọku ti ijọba orilẹede Russia maa n gbe awijare wọn gba.

Ṣiṣe agbodegba fun awọn iroyin aparutu:

Awọn ileeṣẹ iroyin lorilẹede Russia ti ṣe agbodegba fun awn iroyin ti ko fidi mulẹ rara ninu itan wọn, atawọn iroyin to ba ti nii ṣe pẹlu titabuku orilẹede Ukraine.

Ni ọkan ninu awọn iroyin bẹẹ to gbajumọ, ileeṣẹ iroyin orilẹede naa ni dun 2014 ṣe afihan aṣatipo obinrin kan to n fọnrere pe awọn ologun orilẹede Ukraine ti pa ọmọkunrin oun to jẹ ọmọ ọdun mẹta.

Ko tii si ẹri kan pato ti wọn gbe jade lati fi ẹsẹ iroyin ati ifisun ọmọbinrin naa mulẹ ki wọn to gbe e kuro lori afẹfẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Laipẹ yii tun ni awọn ileeṣẹ iroyin kan ni Russia atawọn to fi sọdọ ijọba orilẹede naa ti gbe iroyin nipa fidio kan ti wọn ko firẹ otitọ rẹ mulẹ ninu eyi ti wọn ti ṣe afihan awọn aṣatipo kan tawọn ọmọogun Ukraine n yinbọn lu ni ẹnu aala rẹ pẹlu Belarus.

Ṣọja ti wọn lo oju opo Facebook rẹ fi gbe fidio naa sita pada wa pariwo sita pe wọn ti tọwọ bọ oju opo Facebook naa bi o tilẹ jẹ pe BBC ko lee fidi rẹ mulẹ bya lootọ lawọn oniṣẹ ibi ayelujara tọwọ bẹ oju opo wọnyii.

Aworan orilẹede Ukraine

Pipolongo Ukraine gẹgẹ bii orilẹede to faramọ ihuwasi ijọba Nazi, ti Hitler ko sodi:

Kii ṣe ohun ajeji lati ri awọn iroyin lori awọn ileeṣẹ iroyin ni Russia to n tọka si orilẹede Ukraine gẹgẹ bi orilẹede to faramọ ilana iṣejọba Nazi ti Hitler da silẹ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Fun apẹrẹ̀, ileeṣẹ ọrọ ilẹ okeere ni Russia a maa fi oniruuru iroyin sita lori ayelujara wi pe orilẹede ati Amẹrika dibo tako aba kan ti Russia gbe kalẹ lajọ iṣọkan agbaye to n tako gbigbe iṣejọba Nazi soke. Atẹjade naa n kọ ọ soju opo ayelura pe aadoje orilẹede lo dibo gbe aba naa lẹyin, to si jẹ pe awọn meji yii nikan lo tako aba naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kí ni Russia ń fẹ́ ní Ukraine?

Lootọ ni pe Ukraine ati Amẹrika nikan lo dibo tako aba yii, amọṣa atẹjade ti ileeṣe ọrọ ile okeere Russia ko sọ hulẹhulẹ igbesẹ orilẹede mejeeji yii.

Ukraine ṣalaye pe ohun to mu ki oun tako aba naa ni pe, wọn fẹ loo fun ariwo irọ ni.

Orilẹede Amẹrika ni tirẹ ni atẹjade naa kun fun iboju aṣitumọ iroyin lati ọdọ awọn alaṣẹ orilẹede Russia.

An ologun

Oríṣun àwòrán, EPA