Mo ti sọ tẹ́lẹ̀ pé Yorùbá Nation ò lè “work”, ẹ ti gbàgbé Sunday Igboho s’ẹ́wọ̀n Cotonou – Kemi Olunloyo

Kemi Olunloyo ati Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Kemi olunloyo/Sunday Igboho

Mo ti sọ tẹ́lẹ̀ pé Yorùbá Nation ò lè “work”, ẹ ti gbàgbé Sunday Igboho s’ẹ́wọ̀n Cotonou – Kemi Olunloyo

Olunloyo to sọ pe gbajugbaja akọroyin oniwadii ni oun ti sọ tẹlẹ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu BBC Yoruba pe oun ko faramọ iyapa Yoruba lara Naijiria.

Kemi to jẹ ọmọbinrin gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ri, Ọmọwe Omololu Olunloyo sọ ninu fidio naa pe pipe fun idasilẹ orilẹ ede Yoruba ko le bímọ ire.

Kemi sọ pe ti awọn to n pe fun Yoruba Nation ba mọ nipa ija awọn agba oṣelu meji ilẹ Yoruba, Obafemi Awolowo ati Ladoja Akintola ni, wọn yoo dẹkun pipe fun Yoruba Nation.

Kemi ni “ẹ maa wo ti Yoruba Nation o, ẹ gbiyanju lati da Yorùbá Nation silẹ o.

Ẹ fi ọrọ Awolowo Akintola ṣe arikọgbọn o.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kemi Olunloyo ni ki awọn to ba kere ti ko ba mọ itan naa beere lọwọ awọn agbalagba to mọ ohun to sẹlẹ laarin awọn agba oṣelu meji ilẹ Yoruba náà.

“Emi o faramọ ipe fun idasilẹ Yoruba Nation, amọ, mo wa lẹyin Oloye Sunday Adeyemo lori iṣẹ aanu ti wọn n ṣe fawọn araalu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awon idi wo ni Kemi Oluloyo la kale pe o ṣokunfa ọró rẹ?

Mi o faramọ ki Naijiria pin, orilẹ ede Naijiria kan ni temi o.

Igboho ni iwe igbeluu orilẹ ede Germany lọwọ, Nnamdi Kanu naa ni iwe igbeluu UK dani.

Awọn to ni iwe igbeluu ilẹ okeere lọwọ lo fẹ da ilu ru.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ki lo wa ṣẹlẹ ti Igboho sa kuro ni Naijiria ki wọn to mu un ni Benin Republic?

Ẹgbẹ awọn to n pe Yoruba Nation ni ẹgbẹ to buru julọ ti mo ti ri ri ni Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Wọn ṣe ikowojọ lori pipe fun idasilẹ Yoruba Nation ṣugbọn wọn gbagbe olori wọn, Sunday Igboho si ẹwọn ni Cotonou.

Lẹyin naa ni wọn gbe owo ti wọn fi eto GOFUNDME kojọ salọ.