Òjò owó tó tó N900 biliọ̀nù rọ̀ fún obìnrin kan bí ọ̀rẹ́kúnrin rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ṣe fi fótò ìhòhò rẹ̀ sorí ayélújára

Obinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ile ẹjọ kan ni Texas ilẹ Amẹrika ti fun arabinrin kan ni ẹbun owo $1.2bn eyi to fẹrẹ to N900 biliọnu owo ilẹ Naijiria lẹyin ti wọn ri aridaju pe o faragba ninu iṣẹlẹ gbigba ẹsan lara rẹ ti ọrẹkunrin rẹ tẹlẹ ṣe n fi ihoho rẹ han araye.

Ile ẹjọ pe ẹsun naa ni “Revenge porn” eyi si tumọ si wipe ki eeyan ti iwọ ati rẹ jọ n fẹ ara yin tẹlẹ pinu lati fi aworan ihoho rẹ sita lori ayelujara lẹyin ti tirela ti gba aarin ẹyin mejeji lati le da yẹyẹ ololufẹ tẹlẹ ọhun sita ko si ko iporuru ọkan ba a.

Arabinrin ti ile ẹjọ fun ni orukọ gẹgẹ bii DL lati bo o ni aṣiri lo pe ọrẹkunrin rẹ tẹlẹ lẹjọ lọdun 2022.

Ẹjọ to pe naa fihan pe ọrẹkunrin rẹ tẹlẹ fi awọn fọto ikọkọ rẹ sita lori ayelujara lati fi ṣe yẹyẹ lẹyin ti ija ti pin awọn mejeji niya.

Agbẹjọro arabinrin ọhun ni abajade ẹjọ yii jẹ bibori fun awọn to ba n fara gba ibanilorukọ jẹ nipasẹ ohun to nii ṣe pẹlu ibalopọ.

“Lasiko ti wọn n ba ẹjọ naa yi, ẹbun owo gba ma binu ti wọn yoo fun DL yoo fun un orukọ rere rẹ pada,” Bradford Gilde to jẹ adari ikọ awọn agbẹjọro igbẹjọ naa sọ eyi ninu atẹjade kan.

Awọn agbẹjọro ti kọkọ bere fun ọgọrun miliọnu dollar gẹgẹ bi owo ibanijẹ ti ọrẹkunrin tẹlẹ ọhun ṣe si DL ko to wa di pe ile ẹjọ jọ wọn loju pẹlu biliọnu kan dollar o le diẹ pe ohun ni ki wọn san fun un.

“Ireti wa ni pe iru idajọ owo ti ile ẹjọ pa laṣẹ lori ẹjọ yii yoo fa ọpọlọpọ leti lati ma dan iru iwa buruku yii wo mọ,” Ọgbẹni Gilde fi kun un.

Bawo ni ọrọ ifẹ wọn ṣe bẹrẹ?

Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹgẹ bi awọn iwe to wa niwaju ile ẹjọ, arabinrin yii ati ololufẹ rẹ tẹlẹ bẹrẹ si ni fẹ ara wọn lọdun 2016.

Lasiko ti gbogbo nkan ṣi n dan mọran to n lọ dede laarin wọn, arabinrin naa fi awọn fọto ihoho rẹ ranṣẹ si olujẹjọ lasiko ibadọrẹ wọn.

Lẹyin ti tirela gba aarin wọn kọja lọdun 2021, ọrẹkunrin tẹlẹ yii ba pinu lati fi awọn fọto naa sori ayelujara atawọn oju opo kan to wa fun awọn agbalagba lati maa wo ihoho rẹ lai gba aṣẹ kankan lọwọ DL.

Bakan naa lo tun fi “link” ti eeyan ti le wo aworan ọhun ranṣẹ si awọn ọrẹ arabinrin yii to fi mọ awọn mọlẹbi rẹ.

Lafikun, iroyin ni arakunrin naa tun ni aṣẹ lati taju wo ori foonu DL, awọn oju opo ayelujara rẹ ati atẹjiṣẹ rẹ to fi mọ ẹrọ ayaworan kamẹra to wa ninu ile iya DL eyi to fi n ṣe alami rẹ.

O to akoko kan ti wọn fẹsun kan pe ọrẹkunrin tẹlẹ yii fi ọrọ ranṣẹ si arabinrin ọhun eyi to ka bayii pe: “Oo lo iyoku aye rẹ nipa gbigbyanju ati jijakulẹ lati gbe ara rẹ kuro lori ayelujara. Gbogbo eeyan ti waa pade yoo gbọ iroyin rẹ yoo si woran. Ku idọdẹ o.”

Agbẹjọro DL sọ pe arakunrin naa fi atẹjiṣẹ yii ṣọwọ lati lati fi ọrọ ibalopọ fiya jẹ ẹ ni ati lati da ọpọlọ rẹ laamu.

Ọrẹkunrin tẹlẹ yii ko lee farahan nile ẹjọ lasiko ti igbẹjọ naa n waye ṣugbọn o ran agbẹjọro rẹ lati ṣoju rẹ.