Ẹni bá fẹ́ wọ ọkọ̀ ojú irin báyìí gbọdọ̀ fí ‘’phone number àti NIN’’ rẹ̀ sílẹ̀

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ijọba apapọ Naijiria ti kede pe ẹni to ba fẹ wọ ọkọ oju irin Abuja si Kauna gbọdọ fi nọmba ẹrọ ilewọ wọn silẹ ati nọmba idanimọ Naijiria wọn.

Minisita fun eto irina lorilẹede Naijiria, Mua’zu Sambo lo fi iroyin naa lede lasiko to ṣe ayẹwo si ojuko oju irin naa.

Sambo ti kọkọ sọ saaju pe  Oṣu Kọkanla yii ni wọn yoo ṣi pada.

Amọ ijọba ti wa fi lede bayii pe laarin ọjọ meje ni wọn yoo ṣi pada.

‘’Ọkọ oju irin ko ni ṣi ni Ọjọ Aje, Ọjọ Kejidiinlọgbọn mọ o, laarin ọjọ meje si isinyii ni yoo ṣi’’

Sambo ni awọn agbekalẹ tuntun ti wa ti awọn araalu gbọdọ tẹle ki wọn to ra tikẹẹti wọn.

Awọn ilana tuntun re e…

Aworan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

  • Awọn araalu gbọdọ fi nọnba foonu wọn silẹ ati nọnba idanimọ NIN wọn.
  • Nipa eyi, bi ọkọ oju irin ba ṣe n rin lati idudokọ kan si omiran, a o mọ awọn eniyan ti wọn wọle si inu ọkọ.
  • Nitori naa ẹni ti ko ba ni NIN ko lee wọ ọkọ oju irin mọ ni Naijiria.
  • To ba jẹ ọmọde, agbalagba ni yoo fi orukọ silẹ ati NIN ki wọn ba le mọ ọ.
  • Bakan naa lo fikun un eyi tunmọ si pe agbalagba kan ko ni lee fi orukọ silẹ fun ju ọmọde mẹrin lọ.