Wàhálà àkóso gáréèjì l’Osun, Adeleke ṣèkìlọ̀, APC rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ọ̀gá ọlọ́pàá

Aworan awọn ọdọ kan to n da ilu ru ati aworan gomina ipinlẹ ṣun, Ademọla Adeleke

Oríṣun àwòrán, Other/Adeleke ademola Twitter

Gomina tuntun ni ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti kilọ fun awọn to n da wahala silẹ lawọn ibudokọ gbogbo ni ipinlẹ naa lati lọ tọwọ ọmọ wọn b’ọṣọ bi wọn ko ba fẹ foju wina ofin.

Gomina Adeleke ṣekilọ yii ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Ọlawale Rasheed fi sita lọjọ Aje.

Gomina Adeleke paṣẹ fun awọn agbofinro lati rii daju pe abo to peye ati alaafia waye ni gbogbo ibudokọ ero nipinlẹ naa

Bakan naa lo rọ awọn ọmọ ẹgbẹ ọlọkọ ero nati gba alaafia laaye ki wọn si rii daju pe wọn ko fi aṣẹ si ọwọ ara wọn pa.

Awọn ọmọ ẹgbẹ ọlọkọ ero da rogbodiyan silẹ lori ọrọ akoso gareeji lẹyin ayipada ijọba

Awọn igun kan lẹgbẹ ọlọkọ ero ni ipinlẹ Ọṣun ya bo awọn ibudokọ ero ni ipinlẹ naa lọna ati gba ijọba lọwọ awọn adari to ṣe akoso ẹgbẹ naa ati awọn gareeji ọkọ lasiko iṣejọba ana.

Kii ṣe tuntun mọ ni eto iṣejọba ni Naijiria, paapaa lẹkun iwọ oorun gusu Naijiria pe nigbakigba ti ayipada iṣejọba ba ti waye ni awọn ọmọ ẹgbẹ ọlọkọ ero naa maa n fẹ yii ijọba pada eleyi to si maa n mu ọpọ wahala ati rogbodiyan dani.

Ni iipinlẹ  Ọṣun lọjọ Aiku, lẹyin ibura fun gomina tuntun, Ademọla Adeleke, awọn igun ọmọ ẹgbẹ ọlọkọ ero ya bo sẹkitariati ẹgbẹ naa nibi ti wọn ti da ina wahala silẹ.

Awọn eeyan kan n da ilu ru

Oríṣun àwòrán, other

Arabinrin aboyun kan to jẹ oṣiṣẹ ẹgbẹ ọlọkọ ero nibẹ ni wọn kọlu ti wọn si ja si ihoho.

Bakan naa ni iroyin sọ pe wọn ṣe akọwe owo ẹgbẹ naa, Sunday Akinwale, leṣe lasiko ikọlu naa nibi ti awọn janduku naa ti lo awọn ohun ija oloro bi ibọn, ada ati kumọ loriṣiriṣi.

Awọn ibudokọ ero Ilesha-Osogbo, Oke-fia, Arẹgbẹ, Old garage ati Gbọngan wa lara awọn ibudokọ ti wahala ti bẹ silẹ.

Ẹẹdẹgbẹta ọmọ ẹgbẹ wa ni wọn ti kọlu l’Ọṣun laarin wakati mẹrinlelogun-APC

Aworan ọga ọlọpaa ni NAijiria

Oríṣun àwòrán, Police Nigeria

Pẹlu gbogbo bbi nnkan ṣe n lọ yii ni ẹgbẹ to wa ni atako bayii ni ipinlẹ Ọṣun APC ti wa ke si ọga ọlọpaa Naijiria pe ko  da si ohun ti wọn pe ni bi eto abo ṣe n mẹhẹ ni ipinlẹ naa lọwọ yii.

Ẹgbẹ oṣelu APC ni nnkan bii ẹẹdẹgbẹta awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa ni awọn jjanduku ti kọlu laarin wakati mẹrinlelogun ti ijọba tuntun wọle ni ipinlẹ naa.

Atẹjade kan ti adele alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun, Tajudeen Lawal fi sita sọ pe ọkọ  kan pẹlu akọle ẹgẹ oṣelu APC ni awọn janduku kan tun dana sun lagbegbe Ayetoro nilu Oṣogbo.

“Ikọlu yii ti de awọn ilu bii Ile Ifẹ, Ileṣa, Iwo, Ẹdẹ, Ila ati Ikirun.”