Fídíò, ‘Ká tó rí irú Akala, ó di ‘century’ míì, kò sí olóṣèlú kankan tó máa ń ṣilẹ̀kùn rẹ̀ fún wa l’Ogbomoso’, Duration 6,46

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Adebayo Alao Akala: Àwa àti Ọ̀gá jọ wo bọ́ọ̀lù Egypt àti Nàìjíríà ni; Akala ló sọ èmi alágbe déèyàn tó n bá olówó fò lókè – Aráàlú

Ẹkun o ṣee pamọra ninu ọgba ile oloogbe Abiola Christopher Alao Akala bi awọn araalu ati awọn to ti ṣaanu fun ṣe n fọnrere nipa rẹ.

Ọgbẹni A: Aò mọ̀ pé bàbá máa kú lásìkò yìí, báà ṣe jẹ́ àkàndá tó, ó ti mú wa mọ èèyàn púpọ̀ tó ń fún wa lówó.

“Emi o tilẹ tilẹ tii rẹni to fẹran ilu ẹ bii alao Akala”.

Ile Oloogbe Alao Akala

Arabinrin B: Atẹni to ya odi o, atẹni to ya arọ, ati ẹni torii rẹpe ati eyi ti ko pẹ, ko sẹni ti ọga kii ko mọra.

Amugbalẹgbẹ Akala: A jọ wo bọọlu tan naa ni titi mo fi kuro ni ọdọ wọn ni ago mẹjọ, afi ti wọn tun pe mi pada ni ago mẹjọ kọja, a de inu ile igbọnsẹ la rii ti wọn fọwọ leran ti ọlọjọ ti de.

Ile Oloogbe Alao Akala

Ọmọlẹ́yin Akala ninu Oṣelu: A ti di ọmọ orukan bayii, Ọlọrun o si ṣọ wa.

Ọmọlẹ́yin Akala ninu Oṣelu mii tun ni Otunba ṣẹṣẹ fi ọrọ ranṣẹ si awọn pe wọn fẹ ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi aadọrin fun iyawo rẹ ni boya ọsẹ to n bọ ni.

Ile Oloogbe Alao Akala

Alagbe ti Akala sọ di eeyan pataki: Wọn jẹ ẹnikan to jẹ pe wọn o foju pa wa rẹ ri, wọn o fẹ mọ pe boya ẹnikan alagbe ni to n tọrọ owo.

“Awa to jẹ pe alagbe ta n tọrọ owo ti wọn mọ n fi apo ọra gbe ounjẹ fun wa, awa naa wa n jẹun laarin awo.

Alao to jẹ alaanu tia, aṣoore ma wẹyin ni iku mu lọ”

“Alao sọ wa deeyan, awa dẹni to ba awọn olowo nla nla fo kaakiri”.

Ile Oloogbe Alao Akala
Ile Oloogbe Alao Akala

Ọmọ iṣẹ Akala obinrin: Ká tó rí irú Akala, ó di “century” míì, kò sí olóṣèlú kankan tó máa ń ṣilẹ̀kùn rẹ̀ fún wa l’Ogbomoso.

Ṣe ni wọn n gbadura fun gbogbo idile Akala pe iru rẹ ko ni ṣẹlẹ mọ.