Iléeṣẹ́ ọmọ ogun Naijiria sọ kọ́nẹ́ẹ̀lì 75 di ọ̀gágun oníràwọ̀ kan

Nigeria Army

Oríṣun àwòrán, getty images

Ajọ ọmọgun oriilẹ ni Naijiria lo ti mu agbega ba awọn lọgalọga kan lajọ naa.

Eyi lo n waye lẹyin ifẹyinti awọn ọgagun mẹtalelaadọfa ti wọn ṣe ẹyẹ idagbere fun ni Ọjọru ọsẹ yii.

Ninu awọn ti agbega de ba naa ni awọn ọgagun onirawọ kan mẹtadinlaadọta to di onirawọ meji, ati awọn kọnẹẹli marundinlọgọrin to di ọgagun onirawọ kan.

Gẹgẹ bi adari ẹka iroyin fajọ ologun naa ṣe fi lede, lara awọn ọgagun onirawọ kan tẹlẹ ti wọn fi irawọ kan kun tiwọn ni: W.B Etuk, J.E Osifo, W.M Dangana, T.B Ugiagbe, A.S.M Wase, M.A Abdullahi, B.I Alaya, A.O Oyelade, O.O Arogundade, E.I Okoro, C.R Nnebeife, F.U Mijinyawa, M.T Abdullahi, M Adamu, N.D Shagaya, M.E Onoja ati M.O Erebulu.

Awọn miran to tun di onirawọ meji ni: B.A Ilori, M.O Ihanuwaze, O. Nwachukwu, E.E Ekpenyong, S.I Musa, M. Galadima ati A.P Ahmadu.

Lara awọn to ṣẹṣẹ gba irawọ kan lati ipo kọnẹẹli ni: kọnẹẹli Nwakonobi, M.C Akin Ojo, B.M Madaki, M.O Edide, K.E Inyang, O.O Nafiu, P.A Zipele, O.A Onasanya, M.I Amatso, C.M Akaliro, N.E Okoloagu, A.S Bugaje, A.M Kitchner, S.J Dogo ati J.N Garba.

Bakan naa ni P.T Gbor, S.O Okoigi, A.F Maimagani, P.O Alimekhena, B.I George, I.B Gambari ati A.Y Emekoma wa lara awọn to di ọgagun onirwaọ kan.

Atẹjade naa fi kun-un pe ọga agba ajọ ọmọgun oriilẹ lorilẹede Naijiria, Ọgagun (onirawọ mẹta) Taoreed Lagbaja, ki gbogbo awọn to gba agbega naa atawọn mọlẹbi wọn ku oriire.

O si rọ wọn lati tunbọ gbaju mọ iṣẹ won ki ajọ naa o ma baa kabamọ agbega awọn agbega naa.