A máa pinnu bí ìkọlù sí Iran padà yóò ṣe wáyé – Israel sọ fún UK

Netanyahu àti Lord Cameron

Oríṣun àwòrán, Office of the Prime Minister of Israel

Olóòtú ìjọba orílẹ̀ èdè Israel, Benjamin Netanyahu ti sọ fún akọ̀wé ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè, Lord Cameron pé Israel máa pinnu fúnra rẹ̀ lórí ọ̀nà tí wọ́n máa gbà láti fi ṣe ìkọlù padà sí Iran.

Netanyahu ní ìjọba òun yóò ṣe gbogbo òun tó wà ní ìkáwọ́ òun láti dá ààbò bo orílẹ̀ èdè Isreal.

Lásìkò tí Lord Cameron ń bá Netanyahu sọ̀rọ̀ láti ri pé ìkọlù tí wọ́n máa ṣe padà sí Iran kò lágbára ju bó ṣe yẹ lọ ló sọ̀rọ̀ náà.

Netanyahu ti jẹ́jẹ̀ẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà pé àwọn máa ṣe ìkọlù padà sí Iran lẹ́yìn tí orílẹ̀ èdè náà ṣe ìkọlù sí wọn ní òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí.

Lord Cameron sọ fún Netanyahu pé gbogbo ìgbésẹ̀ tí wọ́n bá máa gbé ni kí wọ́n ri dájú pé kò ní dá ogun ńlá sílẹ̀.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tó ṣe ìpàdé pẹ̀lú Netanyahu ní Jerusalem, Lord Cameron ní òun lọ sí Israel láti fi ìfẹ́ hàn sí wọn lẹ́yìn ìkọlù Iran.

Ó ní kò sí ẹni tó máa jẹ àǹfàní kankan tí ìkọlù Israel padà sí Iran bá kọjá agbára àti pé nǹkan tí àwọn ti ń jẹ́ kó yé gbogbo àwọn tí òun ń bá sọ̀rọ̀ láti ìgbà tí òun ti gúnlẹ̀ sí Israel nìyẹn.

Lẹ́yìn ìpàdé náà, Netanyahu ní Israel máa pinnu lórí ohun tó bá fẹ́ ṣe àti pé gbogbo nǹkan tí àwọn bá máa fi dá ààbò bo orílẹ̀ èdè Israel ni àwọn máa ṣe.

Ọ̀rọ̀ Netanyahu ló ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn orílẹ̀ èdè ẹkùn ìwọ̀ oòrùn ti ṣetán láti fòfin de Iran àti pé ó ní ìwọ̀nba bí wọ́n ṣe lè fi ọwọ́ lé Israel lé èjìká mọ.

Ṣáájú kí Lord Cameron tó ṣe ìpàdé pẹ̀lú Netanyahu ló ti kọ́kọ́ ṣèpàdé pẹ̀lú ààrẹ Israel, Isaac Herzog àti mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèrè Israel, Israel Katz.

Bákan náà ló ní èròńgbà láti ṣe àbẹ̀wò sí olóòtú ìjọba Palestine, Mohammad Mustafa.

Ní orílẹ̀ èdè Italy ni àwọn mínísítà orílẹ̀ èdè G7 yóò ti ṣe ìpàdé, níbi tí èrò wà pé Lord Cameron yóò ti bá gbogbo wọn sọ̀rọ̀ lórí àwọn òfin tí wọ́n fẹ́ fi de Iran.

Àwọn orílẹ̀ èdè bíi UK, US, France àti Jordan ló ran Israel lọ́wọ́ láti ri pé àwọn àdó olóró tó lé ní 300 tí Iran jù sí Israel kò ní ipa púpọ̀.

Ó lé ní àdó olóró 300 tí Iran fi ráńṣẹ́ sí Israel – Iléeṣẹ́ ológun Israel

Joe Biden

Oríṣun àwòrán, @Joe biden

Ileeṣẹ ologun Israel ni o le ni ado oloro ọọdurun to wa lati orilẹede Iran, Iraq ati Yemen si orilẹede Israel ninu ikọlu to waye laipẹ yii.

Agbẹnusọ Ileeṣẹ ologun, Lt Col Peter Lerner lo sọ eyi fun BBC Radio 4.

“Pupọ awọn ado oloro yii ni a ja lulẹ”.

BBC ko le fidi rẹ mulẹ pe ṣe loooto ni iye awọn ado oloro yii

O fikun pe ileeṣẹ ologun ofurufu Israel ri iranlọwọ gba lati ọwọ orilẹede US, UK, France ati awọn mii

Eyi ni igba akọkọ tawọn orilẹ-ede mejeeji yoo fi ọmọ ogun bara wọn ja, lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti wọn ti n naka aleebu sira wọn.

Benjamin Netanyahu ti i ṣe Olootu Isrẹli, ti pepade igbimọ ologun ilu rẹ lori ọrọ yii, lati mọ igbesẹ to ku gan-an.

Ni bayii ṣaa, Iran ti leri ati gbẹsan lara Isreal, lẹyin ikọlu si ileeṣẹ to n ri si irinajo rẹ to wa ni Syria.

Iran fẹsun kan Isrẹli, pe awọn ni wọn kọlu ileeṣẹ naa ti ọga ologun kan fi padanu ẹmi rẹ. Ṣugbọn Isrẹli loun ko mọ nnkan kan nipa rẹ.

Atẹjade ti agbẹnusọ ikọ ologun Israel, Rear Admiral Daniel Hagari, fi sita, sọ pe ọpọlọpọ òkó ibọn ti Iran n yin lawọn ti gba silẹ.

O lawọn tiẹ ri awọn nnkan ija kan ni Isrẹli, ṣugbọn wọn ko pa ẹnikẹni.

Amẹrika yóò pèpàdé àwọn olórí lórí ogun yìí

Aworan Aarẹ Joe Biden

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn alaṣẹ ilẹ Amẹrika pẹlu ijọba Gẹẹsi ti fidi ẹ mulẹ, pe atilẹyin awọn ni ko jẹ ki ikọlu yii ti burẹkẹ.

Aarẹ Joe Biden ilẹ Amẹrika, sọ pe oun yoo ṣepade pẹlu awọn olori (G7) lonii ọjọ Iṣẹgun lati mọ ọna ti wọn yoo gba yanju iṣoro ọhun.

Eyi ni igba akọkọ ti Iran yoo doju nnkan ija kọ Isrẹli, o si ti le ni ado oloro ọọdunrun (300) ti wọn ti ju sibẹ.

Ṣugbọn Isrẹli naa ti ni ko ni i pari sibẹ, wọn lawọn naa ti gbaradi gidi.