Èèyàn méje kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó ṣẹlẹ̀ ní àárọ̀ Kérésìmesì lọ́nà Benin sí Ore

Awọn ẹṣọ oju popo

Oríṣun àwòrán, FRSC Ogun

Bi a ṣe n yọ ayọ ọdun Keresimesi, ibanujẹ ko le wọ ile tọ wa laṣẹ Edumare.

O kere tan, eeyan meje lo dero ọrun ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ laarọọ Keresimesi lopopona mọrosẹ ilu Sagamu si Ijebu Ode.

Ọga agba ajọ ẹṣo oju popo FRSC nipinlẹ Ogun, Ahmed Umar, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, ṣalaye pe ọkọ akero Mercedes Benz kan ni ijamba naa ṣẹlẹ si.

Ọgbẹni Umar ni ere asaju ti ko jẹ ki dẹrẹba ọkọ naa le dari ọkọ ọhun mọ lo ṣe okunfa ijamba yii.

Umar fikun ọrọ rẹ pe lagbegbe Ojuelegba niluu Eko ni ọkọ akero naa ti gbera to si mori le ilẹ Ibo ki ijamba yii to waye ni ago mejila kọja ogun iṣẹju aarọ lori afara Ososa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọga agba FRSC nipinlẹ Ogun ni eeyan mẹtalelọgọta ninu eyi ti ogoji jẹ ọkunrin, mẹẹdogun jẹ obinrin ati ọmọde mẹjọ lo wa ninu ọkọ akero naa.

Umar ni mọkandinlaadọta ninu awọn ero naa lo moribọ lai farapa to fi mọ awọn ọmọde.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọgbẹni Umar rọ awọn awakọ lati rọra sare lasiko ọdun yii ti ọkọ pọ loju popo.

Bakan naa lo rọ wọn lati ye maa rinrin alẹ nigba ti wọn le maa riran daadaa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O tun rọ awọn awakọ lati maa tẹle awọn ofin to de ọkọ wiwa loju popo.

Ọga agba ajọ FRSC ipinlẹ Ogun rọ awọn ti ẹbi wọn ba wa ninu ọkọ naa lati kan si ajọ naa fun ibeere ti wọn ba ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ