Èyí ni ìdí tí Bàbá Kérésì fi máa n wọ aṣọ pupa àti funfun nígbà gbogbo

Baba Keresi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọlọpọ gbagbọ pe Baba Keresi maa n wọṣọ ni ibamu pẹlu aàwọ̀ pupa ati funfun to wa lara agolo nkan mimu ẹlẹrindodo Coke.

Won ro eyi nitori pe ipolowo ọja Coca Cola ni nkan bii ọdun 1030 lo sọ Baba Keresi di gbaju-gbaja.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O dara bẹẹ, ṣugbọn wọn ko da Baba Keresi alaṣọ pupa ati funfun kalẹ lati polowo Coca Cola, ṣugbọn nitori pe o n du ọja pẹlu White Rock l’ọdun 1923 ni.

Ipolowo ọja Baba Keresi o ni Coke

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orisun miran ni aṣọ Baba Keresi ode oni ti wa.

Ọkan lara wọn ni Saint Nicholas. Biṣọọpu Greek ni aye atijọ, to maa n wọ aṣọ pupa ni gbogbo igba to ba ti fẹ ẹ fun awọn alaini ni ẹbun. paapa awọn ọmọde.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ìtàn miran lati ọwọ oṣere Netherlands, Sinterklas, to tun dale Saint Nicholas, to gbajumọ laarin awọn olowo ni New York, bi i Washington Irving ati Clement Clark Moore ni nkan bi ọdun 1800.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awọn mejeeji gbiyanju lati sọ Aisun alẹ Keresimesi di nkan ti gbogbo eniyan yoo wa lori ibusun wọn lati sun, dipo ayẹyẹ ati ariya ita gbangba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọgbẹni Moore jẹ ọ̀kan lara awọn to da Baba Keresimesi ti Amẹrika silẹ – ẹni mimọ to maa n wọ aṣọ pupa, ti yoo si maa fun gbogbo eniyan ni ẹbun, boya wọn fẹ tabi wọn ko fẹ ẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ta a ni Baba Keresi gan an gan?

A le tọ ipasẹ Baba Keresi lọ si ọdọ Biṣọọpu Greek, Nicholas.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ninu ẹ̀sìn Kristiẹni, ọpọ maa n pọn ọn le gẹgẹ bi alaabo awọn ti ko ni iya ati baba, awakọ oju omi ati awọn ẹlẹwọn.

Saint Nicholas.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Olukọtan kan ni Fasiti Manitoba, Gerry Bowler, ṣalaye pe nitori pe Ẹni Ọwọ Nicholas maa n pin ẹbun fun awọn eniyan, ni wọn ba bẹrẹ sii ri gẹgẹ bi baba-isalẹ awọn ọmọde ati onidan to maa n fun nii ni nkan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ṣugbọn, ipolowo ọja lo mu ki Baba Keresimesi ode-oni o gbajumọ.

Ni nkan bi ọdun 1820, ipolowo fun ẹbun ọdun Keresimesi bẹrẹ si ni tan kiri orilẹ-ede Amẹrika, nigba ti yoo si fi di ọdun 1940, Baba Keresi naa ti bẹrẹ si ni farahan daada ninu ipolowo ọja.

Bi ififunni lasiko Keresi ṣe bẹrẹ niyi.