Ifasooto gbòmìnira lẹ́yìn oṣù mẹ́fà látìmọ́lé DSS lórí ẹ̀sùn pé ó ń ṣ’òògùn fún Sunday Igboho

Ifasooto ati Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Lady K

Leyin to lo oṣu mẹfa ni atimọle ajaale ajọ DSS niluu Abuja, Dada Ifasooto ti wọn fẹsun kan pe o ṣoogun fún Sunday Igboho ti gb’ominira.Ọkan lara awọn agbẹjọro Igboho, Pelumi Olajengbesi sọ pe ẹsun ti wọn fi kan Ifasooto ko l’ẹsẹ nlẹ.

Olajengbesi ni iwa ko si ẹni ti yoo mu mi ti DSS n hu lo mu ki wọn ju Ifasooto si atimọle laiṣẹ.

Ọjọ kẹrindinlogun oṣu keje ni ajọ DSS gbe Ifasooto eleyii ti ẹnikẹni ko mọ nipa rẹ.

Eyi ṣẹlẹ lẹyin ọsẹ meji tawọn DSS kọlu ile Sunday Igboho niluu Ibadan nibi ti wọn ti sẹkupa eeyan meji ti wọn si ji eeyan mejila gbe lọ si Abuja.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Olajengbesi ni nigba ti wọn beeli awọn ọmọlẹyin Igboho mejila ni wọn ri pe Ifasooto naa wa ni atimọle DSS l’Abuja.

Olajengbesi ni ohun ti DSS ṣe ko boju mu ati pe o lodi si ofin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lẹyin ti wọn kọlu ile Oloye Igboho tan ni awọn ọlọpaa Interpol tun mu un lorilẹede Benin Republic lọna irinajo rẹ si Germany.

Ati igba naa lawọn lẹgbẹlẹgbẹ bii Afenifere, Ilana Omo Oodua atawọn ẹgbẹ mii ti n pe fun itusilẹ rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Amọ, Igboho ko tii gba ominira ni ahamọ niluu Cotonou to wa titi di asiko yii.

Ẹwẹ, ile ẹjọ giga niluu Ibadan tun paṣẹ pe ki DSS san ogun biliọnu naira owo gba ma binu pẹlu ikọlu ti wọn ṣe si ile rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ṣugbọn ajọ DSS ko tii pa aṣẹ ile ẹjọ mọ titi ti asiko ti a kọ yii bakan naa.