Kò sí ohun tó jọ pé ìjọba wa fẹ́ yí ìdájọ́ Rahman Adedoyin padà – Adeleke

Rahman Adedoyin

Oríṣun àwòrán, @AAdeleke_01

Ijọba ipinlẹ Osun ti sọ pe irọ patapata ni iroyin to ni oun n pinnu lati darijin Rahman Adedoyin lẹyin ti ile ẹjọ dajọ iku fun lori iku Timothy Adegoke.

Adedoyin atawọn eeyan mẹfa mii ni ọlọpaa fi ṣikun ofin mu ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2021 lẹyin iku akẹkọọ naa nile itura Adedoyin.

Lẹyin igbẹjọ ẹsun naa ni ile ẹjọ sọ pe Adedoyin jẹbi ẹsun ipaniyan, to si dajọ pe ki wọn lọ yẹ igi fun titi ti ẹmi yoo fi bọ lẹnu rẹ.

Ki ni ijọba ipinlẹ Osun sọ?

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Gomina Ademola Adeleke, Olawale Rasheed fi lede, o ni ko si ohun to jọ pe ijọba to wa lori oye yoo tọwọ bọ eto idajọ.

O ni “ẹni ibi ni gbogbo awọn to n gbe iroyin ẹlẹjẹ bẹẹ kiri lọna ati ba orukọ gomina jẹ.”

“Gomina Adeleke ko ni lo agbare rẹ gẹgẹ bii gomina lati tọwọ bọ eto idajọ lailai.”

“O ṣe pataki lati jẹ ki awọn araalu mọ pe gomina tabi ẹgbẹ oṣelu rẹ ko ni ohun ikọkọ kankan lati ṣe pẹlu igbẹjọ naa yatọ si pe ki erongba awọn araalu fun idajọ ododo wa si imuṣẹ.”

Rasheed tun sọ pe gomina ipinlẹ Osun ko fi igba kankan ni ajọṣepọ pẹlu Adedoyin, bẹẹ si ni ko ṣetan lati ṣe makaruru lọna ati dena idajọ ododo.

“A rọ awọn araalu lati maṣe tẹti si ahesọ ọrọ to n kakaiti pe ijọba wa fẹ darijin Adedoyin lati yi idajọ rẹ pada.”

Lẹyin naa lo gba awọn araalu lamọran lati maṣẹ naani iroyin ẹlẹjẹ ti awọn kan n gbe kiri lori ayelujara pe gomina Adeleke fẹ darijin Adedoyin.

O tun dupẹ lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Osun fun atilẹyin wọn fun ijọba Adeleke ni gbogbo igba.

Ẹwẹ, ṣaaju ni awọn iroyin kan ti kọkọ jade ṣaaaju asiko yii pe họwuhọwu kan n waye laarin adajọ ipilẹ Osun ati Gomina Adeleke.

Iroyin naa ni eredi họwuhọwu naa ko ṣẹyin igbẹjọ Adedoyin lori iku Adegoke, ati pe gomina Adeleke fẹ mọọmọ jẹ ki adajọ naa fẹyinti nigba ti asiko ifẹyinti rẹ ko tii to.