DDS ní kí n di ológbò bíi Sunday Igboho, ojú mi rí tó ní àhámọ́ DSS l’Abuja- Ifasooto

Sunday Igboho ati Dada Sooto Arifanlajogun

Oríṣun àwòrán, Dada Arifanlajogun

Oju mi ri to lahamọ ajọ DSS l’Abuja, wọn ni ki n d’ologbo bi Oloye Sunday Igboho.

Babalawo Dada Ifasooto ti ajọ DSS ti mọle lori ẹsun pe o n ṣe oogun fun ajijagbara ilẹ Yoruba, Igboho lo sọ bẹẹ.

Ifasooto gba ominra lọjọ Ẹti tii ṣe aisun ọdun Keresimesi lẹyin to ti lo oṣu mẹfa lahamọ DSS niluu Abuja.

Ifasooto ni oun o ba Igboho pade ri oun kan maa n gbọ orukọ lasan ni.

”Lootọọ ni mo ti gbọ oriṣiiriṣii nipa Oloye Igboho nipa akitiyan rẹ lori iwọde idasilẹ Yoruba nation kaakiri ilẹ Yoruba ki wọn to mu un.

Ṣugbọn emi ati Igboho ko to pade ri, amọ lẹyin ọ rẹyin ni mo ri wi pe mo ti ṣiṣẹ iwosan fun ọmọlẹyin rẹ kan, Tajudeen Irinloye ri.

Lọjọ kan ni mo pe Tajudeen to n fi ọkada ṣiṣẹ niluu Ibadan lori ago lati beere nipa ara rẹ.

Amọ, DSS ti gbe e lọjọ kinni oṣu keje nigba ti wọn ṣe ikọlu sile Igboho ni Ibadan, emi o si mọ nkan kan.

Ọwọ awọn DSS ni foonu rẹ wa nigba ti mo pe, ṣadeedee ni mo ri awọn ẹṣọ ajọ DSS mẹrin lọjọ kẹrindinlogun oṣu keje nile mi.

Wọn Tajudeed wa lahamọ lọdọ awọn nitori naa awọn si wa lati wa gbe mi naa lọ.

Bayii ni DSS ṣe gbe mi lọ si Abuja lai sọ ẹsẹ ti mo ṣẹ gan an fun mi.

Ọkan lara awọn ọga sọ fun mi pe lara awọn ẹṣọ DSS to lọ mu Igboho ni wọn wa mu emi naa.

O bẹrẹ sini fi mi ṣe yẹyẹ pe ki n poora tabi ki n di ologbo bi Igboho ṣugbọn mo dahun pe n ko le poora tori n ki ṣe ọdaran.

Wọn kọkọ gbagbe mi si atimọle fun oṣu mẹta gbako, nibẹ ni mo ti ni aisan ẹjẹ ruru.

Wọn gbe mi lọ si ile iwosan, wọn tun gbe mi pada si atimọle lati ile iwosan.

Burẹdi kekere ati miliiki Cowbell ni wọn maa n fun mi fun ounjẹ aarọ, raisi ti ko dun un wo loju ni wọn maa n gbe wa fun mi lọsan an.

Ohun ti wọn sọ fun mi naa ni pe mo maa n ṣe oogun fun Igboho eleyii ti kii ṣe otitọ rara.

Wọn tun sọ fun mi pe mo maa n ṣe oogun fawọn ọmọ ẹgbẹ ajiajagbara ilẹ Ibo, IPOB, eleyii to jẹ irọ nla tori mi o tii de ilẹ Ibo ri laye mi.

Amọ, lọjọ kẹrinlelogun ni wọn sọ fun mi pe ki n dupẹ agbẹjọro Pelumi Olajengbesi to ja fun mi ati pe iwadii awọn fihan pe mi o mọwọ mẹsẹ.

Wọn kilọ fun mi lati maa kiyesara pẹlu ohun ti mo ba n ṣe bi bẹẹ kọ awọn yoo da mi pada si atimọle.

Bi mo ṣe lo oṣu mẹfa latimọle niyẹn laiṣẹ, amọ mo dupẹ lọwọ Eleduwa pe ọdun Keresimesi ko ba mi ni atimọle DSS,” Ifasooto lo ṣalaye bẹẹ.