Akintoye àti Igboho ń sọ tiwọn ni, àtúntò ni a dúró fún – Afenifere

Akintoye/Igboho

Oríṣun àwòrán, Akintoye/Igboho

Awọn agba Yoruba kan atawọn onimọ nipa ọrọ to n lọ ti sọ pe kii ṣe ọrọ ki ilẹ Yoruba yapa kuro lara Naijiria lo kan bayii.

Eyii lo n jẹyọ lẹyin ti awọn aṣaaju ẹgbẹ Ilana Omo Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye ati Sunday Igboho kọ lẹta si Aarẹ Bola Tinubu pe ko gbe igbimọ ti yoo ṣeto bi Yoruba yoo ṣe fi Naijiria silẹ dide.

Lẹta naa ni wọn kọ lẹyin eyii ti wọn kọkọ fi ranṣẹ lọdun 2022 lasiko ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari.

“Atunto ni Afenifere n fẹ, a ko fẹ Yoruba Nation”

Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, akọwe ẹgbẹ Afenifere nigba kan ri, Baṣọrun Sehinde Arogbofa sọ pe awọn ko fẹ ki Naijiria pin.

O ni “A ko fẹ ki Naijiria pin o, a n fẹ ki nnkan daa si ni o.

“Ki ijọba Tinubu to de lawọn kan ti n sọ pe ki Naijiria pin ṣugbọn Afenifere ko fẹ gbogbo nnkan wọnyẹn, a n fẹ ki Naijiria dara si ni o.

“Iṣoro pọ, Aarẹ to wa nibẹ bayii ko tii to ọdun kan to de ibẹ, niṣe lo yẹ ki a maa fun ni imọran, ki a si maa sọ oju abẹ niko fun un.

“Iyẹn la ṣe n sọ pe ti a ba le jẹ ki ẹkun kọọkan maa ṣe eto ara rẹ bii ti aye awọn baba wa Awolowo ati Azikwe, nnkan yoo dara.

“Ni ti pinpin yẹn ko fi gbogbo ara ba wa lara mu, ẹ jẹ ki a ran ẹni to wa nibẹ lọwọ, ki a si ni suuru diẹ.”

“O yẹ ki Tinubu ba gbogbo awọn ẹgbẹ to n jijagbara ṣepade”

Nigba to n da si ọrọ naa, olori ẹgbẹ ajọ Journalist for Democratic Rights to n maa pari aawọ laarin awọn ẹgbẹ ajijagbara nilẹ Yoruba ati ni Naijiria, Adewale Adeoye, sọ pe ofin United Nations fun awọn eeyan to ba n sọ ede kan lẹtọ lati sọ bi wọn ṣe fẹ maa dari ara wọn awọn.

Adeoye ni o yẹ ki Tinubu ṣe ipade pẹlu awọn to n jijagbara gẹgẹ bo ṣe ṣepade pẹlu ẹgbẹ Afenifere laipẹ yii.

O ni “Nigba ti Goodluck Jonathan de ori oye, o pe awọn Ijaw to n ja, o ba wọn sọrọ pe ẹ wa, ijọba tiwa niyii, njẹ iru ipade bẹẹ ti waye laarin awọn olori wa atawọn ẹgbẹ ti a n sọ yii.

“O yẹ ki ijọba apapọ pe awọn olori ẹgbẹ ti a n sọ wọnyii si ijoko, ko bere pe ki ni ẹ n fẹ.”

Ninu ọrọ Adeoye, ọdun mẹta sẹyin ni baba Akintoye ati Sunday Igboho bẹrẹ ijijagbara fun ilẹ Yoruba, ṣugbọn awọn ẹgbẹ kan ti wọn ti da silẹ lọjọ to ti pẹ n fẹ irufẹ nnkankan naa.

O ni “Awọn kan wa ti wọn ko tii sọrọ, OPC ko tii sọrọ, OLM ko sọrọ, Vigilante Group ko sọrọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.”

O pari ọrọ rẹ pe ti ijọba apapọ ba le maa ba awọn janduku to n ji eeyan gbe dunadura ninu igbo, o yẹ ko le jiroro pẹlu awọn ajijagbara to kan n ṣe iwọde kiri igboro lasan.

Tinubu, àkókò tó fún Yoruba láti kúrò lára Naijiria – Igboho, Akintoye

Igboho and Akintoye

Oríṣun àwòrán, Igboho/Akintoye

Awọn aṣaaju ẹgbẹ Yoruba Nation, Ọjọgbọn Banji Akintoye ati Oloye Sunday ‘Igboho’ Adeyemo ti kọ lẹta si Aarẹ Bola Tinubu pe ko gba ilẹ Yoruba laaye lati yapa kuro lara Naijiria.

Lẹta ọhun, ti wọn kọ lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii ni Akintoye, Igboho ati Ola Ademola buwọlu.

Wọn ke si Tinubu pe ko gbe igbimọ kan kalẹ ti yoo jiroro lori bi Yoruba yoo ṣe fi Naijiria silẹ.

Iwe atẹjiṣe yii lo n jade lẹyin ọsẹ kan ti awọn kan ti wọn pe ara wọn naa ni ọmọ ẹgbẹ Yoruba Nation kọlu ọọfisi ijọba ipinlẹ Oyo, ki ọwọ awọn agbofinro to tẹ wọn.

Awọn ajijagbara naa, ti iye wọn to mọkandinlọgbọn ti foju bale ẹjọ ti adajọ si ni ki wọn ṣi maa lọ gba atẹgun ninu ẹwọn fun akoko diẹ na.

Ki lo wa ninu lẹta Akintoye ati Igboho?

Ninu lẹta ọhun ni awọn ajijagbara fun ominira ilẹ Yoruba naa ti sọ pe awọn ko fẹ atunto Naijiria, bi ko ṣe ki Yoiruba yapa.

Wọn ni “Ọlọla julọ, inu wa dun lati kọ lẹta yii lorukọ ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ọmọ Yoruba kaakiri agbaye.

“A n fi lẹta yii sọwọ si yin lẹyin eyii ti a kọkọ fi ranṣe lọjọ kẹfa, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022, eyii ti a fun aṣaaju yin, Aarẹ Muhammadu Buhari, to jẹ Aarẹ Naijiria nigba naa.

“Lati ọdun 2015 ni awọn darandaran ti n ṣekupa awọn eeyan ni Najiria, lara awọn ti wọn si n pa ni ipakupa ni awa Yoruba wa, wọn n ba ere oko jẹ, wọn n kọlu awọn abule wa, bẹẹ ni wọn n ji awọn obinrin atawọn ọmọ wẹwẹ gbe lati gba owo gọbọi, eyii ti wọn fi n sọ ilẹ Naijiria di ti ara wọn nikan.”

Lẹta naa tẹsiwaju pe awọn ọdaran darandaran ọhun ti ṣekupa ọpọ eeyan ni aringbungbun Naijiria, ti wọn si gba ilẹ awọn eeyan ọhun gẹgẹ bii tiwọn.

“Nilẹ Yoruba to jẹ tiwa, ojojumọ lawọn darandaran n paayan ti wọn si n ji awọn eeyan gbe, eyii to ti mu ki ọpọ araalu fi oko wọn silẹ to si n mu iyan ba awọn eeyna wa.

“Awọn iwa tawọn darandaran yii n wu jẹ eredi pataki fun wa lati sọ pe a fẹ yapa kuro lara Naijiria ki a si ni orilẹede tiwa to da duro.

“A ko fẹ atunto Naijiria”

“Ọpọ awọ ọmọ Yoruba ni ko ni ireti kankan ninu atunto ti awọn ọmọ Yoruba kan bii awọn baba wa ninu ẹgbẹ Afenifere n bere fun.

“Eredi ni pe a mọ pe atunto ko ni di awọn ọdaran darandaran lọwọ ninu ikọlu wọn si wa nitori ọmọ Naijiria ni wọn, wọn si ni ẹtọ lati lọ sibikibi to ba wu wọn lorilẹede wọn.

Akintoye ati Igboho sọ pe ko din ni ẹgbẹrun mọkandinlọgbọn ọmọ Yoruba ti awọn darandaran ti ṣekupa laitọjọ.

Akoko si ti to fun Aarẹ lati gbe igbimọ dide ti yoo jiroro lori bi Yoruba ṣe maa yapa kuro lara Naijria.