Kí ni ẹgbẹ́ CAN sọ sí ikú ọkùnrin ẹlẹ́ran tí wọ́n sọ lókò pa ní Sokoto torí ó bú Anabi?

Aworan CAN ati Oloogbe Usman

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi (Christian Association of Nigeria) to ti fi atẹjade sita ni Ọjọbọ lati fesi si iṣẹlẹ ọkunrin Musulumi kan ni Sokoto ti orukọ rẹ n jẹ Usman Buda.

Ninu atẹjade naa, aarẹ ẹgbẹ CAN, Alufaa Daniel Okoh fi ọrọ ibanikẹdun rẹ ranṣẹ si mọlẹbi arakunrin to ti di oloogbe naa.

Ẹgbẹ CAN funpe si ijọba lati rii pe wọn n da abo bo gbogbo araalu lai fi ti ẹsin wọn ṣe.

Alufa John Joseph Hayep to jẹ adari ẹka ẹgbẹ naa ni ilu Kaduna ba ileeṣẹ iroyin BBC sọrọ to si sọ pe idi pataki ti awọn ṣe fi atẹjade yii sita ni lati gba awọn eeyan niyanju pe ki wọn maa fa ẹni to ba ṣẹ le awọn alaṣẹ lọwọ dipo ki wọn maa gbe iru igbesẹ ti wọn gbe yii lai ṣewadii kankan.

“A rii pe latẹyin wa, bi wọn ba pa awọn Musulumi, awọn Kristẹni maa n dakẹ, bi wọn ba pa awọn Kristẹni, awọn Musulumi naa maa n dakẹ, nibayii, a gbagbọ pe ọmọ Naijiria ni wa, awọn Kristẹni gbudọ da abo bo awọn Musulumi, awọn Musulumi naa si gbudọ da abo awọn Kristẹni.”

O fi kun un pe ohun to ṣẹlẹ yii ko tọ tori pe o lodi si awọn ikọni ẹsin, “a si fi ibanikẹdun wa ṣọwọ si ẹbi rẹ, Ọlọrun nikan lo mọ ohun ti wọn n la kọja bayii, ko sẹni to lee sọ imọlara wọn”.

Adari CAN ni Kaduna

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gẹgẹ bi aarẹ ẹgbẹ CAN ṣe sọ, o fi kun un pe gbogbo araalu gbọdọ ni ẹkọ wipe bi wọn ba na ika alebu tabi ẹsun si ẹnikan, ko tumọ si pe o ti da ọran ayafi igba ti iwadii ba waye ti wọn si fi aridaju ohun ti wọn fi ẹsun rẹ kan an mulẹ.

Ẹgbẹ CAN wa sọ fun awọn ileeṣẹ agbofinro pe ki wọn fi panpẹ ofin gbe awọn to pa ọkunrin naa ki awọn eeyan le mọ pe iwa to lodi si ofin ni ati lati dena ki iru rẹ ma tun waye lọjọ iwaju.

Wọn ni bi wọn ṣe pa arakunrin yii jẹ aṣa atijọ wọn si koro oju si iwa kiwa to jẹ iwa ipa ti awọn eeyan ba n fi orukọ ẹsin ṣe.

Okoh rọ awọn adari ẹsin lorilẹede Naijiria ati awọn altilẹyin wọn lati mu igbelarugẹ ba ibaraẹnisọrọ laarin oniruuru ẹsin ati ibagbepọ alafia ninu ilu.

“CAN nigbagbọ ninu ẹtọ ẹni lati ṣe ẹsin to ba wu u ati sisọrọ alafia nipa igbagbọ ti onikaluku ba ba. A fi ibanikẹdun wa ranṣẹ si ẹbi ati ara oloogbe. A o tẹsiwaju lati maa pe fun idaabo bo ẹmi ati ẹtọ awọn araalu lai fi ti ẹsin wọn ṣe. Ọkan wa ati adura wa wa pẹlu idile Buda lasiko to nira yii.”

Gẹgẹ bi iroyin to tan kaakiri, okuta ni wọn sọ pa Usman titi to fi ku ni Sokoto alatari pe wọn ni o sọrọ alufansa si Anabi.

‘Onínú ire tó fẹ́ràn ẹbí ni arákùnrin tí wọ́n pa ní Sokoto lórí ẹ̀sùn pé ó bú Anabi’

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn eniyan to mọ arakunrin Usman Buda to padanu ẹmi rẹ ni Ọjọ Aiku ni ilu Sokoto ti sapejuwe iru eniyan ti ọkunrin naa.

Awọn ara ilu to mọ ọkunrin naa to n ta ẹran ni eniyan daradara ni, to si ni ifẹ awọn eniyan ati mọlẹbi rẹ.

Bakan naa ni wọn se apejuwe rẹ gẹgẹ bi ẹni ti ko fi ẹsin Islam sere, to si n tọku awọn mọlẹbi.

Arakunrin Buda naa ni wọn sekupa lori ẹsun pe o sọ ọrọ tako ẹsin Islam.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ni Usman to n ta ẹran ni ọja Dankure ni ilu Sokoto lo n jiyan pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ to jẹ igun ẹsin miran, ti ọrọ naa si da nkan miran to jasi iku rẹ.

Kilo fa iṣẹlẹ iku Arakunrin Usman ti wọn sọ ni okuta pa?

Fidio ni awọn eniyan n pinka lori ẹrọ ayelujara nibi ti awọn kan ti n ju okuta lu Usman, ti wọn si n ke ‘’Allahu Akbar’’.

Arakunrin Sani to ba BBC News Pidgin sọrọ ni Usman fẹran ẹsin rẹ de ọkan, ti ko si ni sọ ọrọ tabuku ẹsin ọhun.

‘’Usman jẹ ẹlẹsin otitọ Islan nitori naa ko le sọ ọrọ kubakugbe nipa ẹsin Islam.

Bakan naa lo fẹran mọlẹbi rẹ nitori naa ibanujẹ ọkan lo jẹ fun wa nigba ti a gbọ nipa iṣẹlẹ naa, nitori a mọ pe ko lee waye bẹẹ lai si pe ejo ni ọwọ ninu.

Sani ni oun ti mọ Usman fun ogun ọdun ti kii si se alagabagebe, to si ni ọrọ igun si igun lo fa iṣẹlẹ naa.

Usman n sọ fun awọn eniyan pe Ọlọrun nikan ni o yẹ ki eniyan gbadura si ki o si bẹbẹ fun nkan lọwọ rẹ.

Awọn eniyan kan wa bẹbẹ fun owo ni asiko naa to si sọ fun wọn pe Allah nikan lo yẹ ki eniyan maa bẹ ko fun ni nkan.

Awọn eniyan binu si ọrọ ti o sọ, ti wọn si sọ di ọrọ miran mọ lọwọ, ki wọn to sekupa a.

Ẹlomiran to tun sọrọ nipa rẹ, Zainab Abubakar ni Usman ni iyawo ati awọn ọmọ pupọ sile, ti ipaya si ti deba wọn lẹyin isekupani baba wọn, to n pese ounjẹ fun wọn.

Ọrẹ rẹ miran, Mubarak Balle ni awọn mejeeji ni wọn jọ ma n lọ kirun papọ, to si jẹ onimọ ẹsin nipa igun Sunni ni, amọ to ni o da oun loju pe awọn to dana sun naa kii se ẹlẹsin igun Sunni.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii n lọ lọwọ

Lori iṣẹlẹ yii, ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ sokoto ti fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.

Wọn ni ni nnkan bi aago mẹsan-an kọja ogun iṣẹju ni owurọ ọjọ Aiku, ni awọn gba ipe pajawiri nipa nnkan to ṣẹlẹ.

Agbẹnusọ ọlọpaa, ASP Ahmad Rufa’i sọ ninu atẹjade kan pe ni kia ti awọn gba ipe naa ni kọmisanna ọlọpaa, ati ọga ọlọpaa agbegbe Kwanni, ko awọn ọlọpaa lọ sinu ọja naa.

“Nigba ti a de ibẹ, awọn eero to n lẹ Usman ni okuta salọ kuro nibẹ, ti wọn si fi silẹ sibẹ. Lati ibẹ la ti gbe e lọ sileewosan Usmanu Danfodio Teaching Hosspital niluu Sokoto, ṣugbọn o pada kú.”

Agbẹnusọ ọlọpaa sọ pe iwadii ti n lọ lori bi ọwọ yoo ṣe tẹ awọn apaayan naa.

Iru iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ si akẹkọọ kan nipinlẹ Sokoto

Ọdun 2022 ni iroyin iru iṣẹlẹ bayii tàn kaakiri agbaye, nigba ti awọn akẹkọọ ile ẹkọ ikọṣẹ olukọ niluu Sokoto, sọ okuta pa akẹkọọbinrin kan, Deborah Yakubu nitori ẹsun kan naa.

Ni owurọ ọjọ kejila, oṣu Karun-un, ni awọn akẹkọọ naa wọ Deborah jade si ita gbangba lati inu yaara rẹ, fun ẹsun pe o sọrọ odi si anabi ni oju opo Whatsapp.

Lẹyin naa ni wọn lẹ ẹ ni okuta pa, ki wọn o to dana sun oku rẹ.