Èèyàn tó tó 50 pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀ àjàgbé

Aworan

Oríṣun àwòrán, Google Maps

O to eeyan mẹrindinlaadọta to ti jẹ Ọlọrun nipe nibi ijamba ọkọ ajagbe kan to waye lorilẹede Kenya

Eyi waye lẹyin ti ọkọ ajagbe kan sọ ọwọ ọkọ rẹ nu ni ikorita Londiani niluu Kericho, to si yawọ aarin ero.

Ileeṣẹ Ọlọpaa orilẹede Kenya ti fi idi isẹlẹ naa mulẹ

Ọga Agba ileeṣẹ Ọlọpaa, Geoffrey Mayek ni eeyan miiran to to ọgbọn ni ye lo tun farapa yanayana nibi isẹlẹ naa ati pe o sese ko ju bẹ lọ.

O tẹsiwaju pe o sese ki eeyan kan tabi meji wa labẹ ọkọ ajagbe naa to subu lulẹ.

Tom Mboya Odero, Ọga ọlọpaa ẹkun agbegbe miran ni ọkọ ajagbe naa n lọ irinajo lọ si Kericho ni o sọwọ rẹ nu to si lọ kọlu ọkọ ayọkẹlẹ mẹjọ, ọpọlọpọ ọkada, awọn eeyan to wa lẹgbẹ titi, awọn ontaja ati awọn miiran to n se karakata wọn.

Ki ni oṣojumikoro sọ?

Osojumikoro sọ fun ileeṣẹ iroyin Kenya wipe dẹrẹba ọkọ ajagbe n pẹ ọwọ lati le ma le kọ lu ọkọ ayọkẹlẹ kan to taku si oju ọna

Aarẹ Kenya, Williams Ruto ni ọkan oun bajẹ lori isẹlẹ ijamba ati pe pupọ awọn to ba isẹlẹ naa lọ jẹ ọdọ pẹlu ọjọ ọla rere pẹlu awọn eeyan to gbaju isẹ ojọ wọn.

“A n rọ awọn dẹrẹba lati ma se ọpọlọpọ suuru loju opopona paapa lasiko ti gbogbo wa mọ pe ojo wa nita