Bíṣọ́ọ̀bù tí wọ́n gún lọ́bẹ lóun ti dáríji àwọn tó kọlu oun

Aworan ibi iṣẹlẹ na

Oríṣun àwòrán, Ibi iṣẹlẹ naa/Others

Gbajugbaja Biṣọọbu ijọ Sydney ti wọn gun lọbẹ lọjọ Aje, ọsẹ yii ti sọ pe ara oun ti n ya, ati pe oun ti dariji gbogbo awọn to wa ṣe ikọlu si oun.

Biṣọọbu naa, Mar Mari Emmanuel ninu ohun to fi ranṣẹ sita laipẹ yii tun rọ gbogbo awọn to n fi ẹhonu han lati gba alaafia laaye.

Awọn ọlọpaa sọ pe bi wọn ṣe kọlu Biṣọọbu naa lori Pẹpẹ nii ṣe pẹlu ọrọ ẹsin, to si wa lori ayelujara.

Niṣe ni ọrọ di faakaja niwaju ita ṣọọṣi naa, The Good Shepherd Church, nigba ti awọn ololufẹ Biṣọọbu Emmanuel sare debẹ lati gba a silẹ.

Ọmọ-ọdun mẹrindinlogun to fi ara pa nibi iṣẹlẹ ọhun ni wọn ti fi kele ofin gbe, ṣugbọn ti wọn ko tii fi ẹsun kankan kan an.

Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni awọn alakoso ko to tii sọ patọ iru ẹsin ti ọmọ naa n sin.

Ni ibẹrẹ ọsẹ yii, ọga agba ajọ to n ri sọrọ eto aabo lorileede Australia, Australian Security Intelligence Organisation, Mike Burgess sọ awọn ti ṣe iwadii lori fọnran ibi ti ọmọkunrin naa ti n sọrọ pẹlu ede larubawa, to si n darukọ ‘Ojiṣe’.

Ninu ọrọ oniṣeju mẹrin ti Biṣọọbu Emmanuel fi sita, eyi ti awọn alakoso ijọ rẹ gbe jade sori ikanni ayelujara wọn l’Ọjọbọ, o ni “mo ti dari ji ẹni to huwa yii.

“Maa si maa fi ojoojumọ gbadura fun ẹ. Ati pe ẹnikẹni to le wu ko ran ẹ niṣe yii, mo forijin awọn naa lorukọ Jesu.”

Bakan naa lo tun fi kun ọrọ rẹ pe ara oun ti n mokun, ko si sohun to yẹ ko jẹ ibẹru fẹnikẹni.

Ki lo ti kọkọ ṣẹlẹ tẹlẹ?

Sydney Church Stabbing: Ìkọlù sí ṣọ́ọ̀ṣì kò yàtọ̀ sí ti àwọn agbébọn – Ọlọ́pàá

Aworan alufaa

Niṣe ni ọrọ di bi o ko le lọ, ki o yago lọna lọjọ Aje, ọsẹ yii nigba ti wọn sọ pe ọmọdekunrin, ọmọ ọdun mẹrindnlogun kan ṣe ikọlu si ile ijọsin Assyrian Christ The Good Shepherd Church to wa niluu Sydney lorileede Australia.

A gbọ pe asiko ti awọn olujọsin n gbadura idakẹjẹ, eyi ti wọn n pe ni ‘Mass’ lọwọ ni ọmọ naa jawọ ṣọọṣi ọhun.

Ileeṣẹ ọlọpaa to fidi ikọlu ọhun mulẹ sọ pe ikọlu naa ko yatọ si ti awọn agbebọn, nibi ti ọpọ awọn olujọsin, to fi mọ awọn olori ijọ ti farapa.

Biṣọọbu kan, Alufa kan ati awọn olujọsin ni wọn fara gbọgbẹ lasiko ikọlu ọhun.

Awọn mẹrin ni iroyin fi to wa leti pe wọn farapa kọja sisọ, koda lara awọn to tẹle ọmọ naa lọ ṣe ikọlu yii fọra gbọgbẹ ko to di pe wọn salọ.

Gbogbo bi iṣẹlẹ ọhun ṣe waye lo wa lori itakun ayelujara ṣọọṣi naa, eyi to mu ki ibẹrubojo ba ọpọ awọn to n wo o lọwọ.

Awọn ọlọpaa sọ wi pe bo tilẹ jẹ pe iwadii awọn ṣi n lọ lọwọ, ṣugbọn sibẹ, wọn jẹ ko di mimọ pe ko si nnkan meji to fa ikọlu naa, to kọja iwa ilara ẹsin.

Sibẹ awọn ọlọpaa kọ lati sọ iru ẹsin ti awọn to ṣe ikọlu naa n ṣe, lati le ma jẹ ki ikọlu naa gba ọna miran yọ.

Aworan ati fọnran ikọlu naa lo gba ori ikanni ayelujara kaakiri lalẹ ọjọ Aje, eyi to mu ki awọn eeyan dide lati sare lọ sibẹ.

Pupọ awọn oluworan la gbọ pe wọn kọlu awọn ọlọpaa ti wọn lọ lati doola ẹmi awọn olujọsin naa.

Ọlọpaa meji lo farapa lasiko ti awọn eeyan kọju ija si wọn, bẹẹ ni mọto ọlọpaa ti ko din ni mẹwaa tun bajẹ.

Gbogbo awọn olutọju ti wọn lọ tọju awọn to farapa ninu ṣọọṣi naa ni wọn lọ farapamọ lati doola ẹmi ara wọn fun bii wakati mẹta, ko to di pe ohun gbogbo lọ silẹ.

Loju ẹsẹ la gbọ pe olori ilu, Anthony Albanese ti pe ipade pajawiri awọn agbofinro kaakiri, lati wa ọna abayọ ti wọn yoo fi dẹkun ohun to ṣẹlẹ.

“Orileede to nifẹ alaafia ni wa. Ko si aaye fun iwa ipa tabi ilara. Ẹ ma fi ofin tabi idajọ sọwọ ara yin.”

Nigba to n sọrọ laarọ oni, Tuside, kọmiṣanna ọlọpaa tuntun ni New South Wales (NSW) sọ pe Biṣọọbu ati Olori ijọ ti wọn kọlu ti n gba itọju lọwọ, ati pe wọn tun ti n ṣiṣẹ abẹ fun wọn.

O ni anfaani nla ni wọn ri lati tun ṣi wa laye.

Father Isaac Royel lorukọ Alufa, nigba ti wọn pe orukọ Biṣọọbu ni Mar Mari Emmanuel. Ọdun 2011 ni wọn yan Biṣọọbu Emmanuel si ijọ naa, to si ti ilu mọ-ọn ka.

A gbọ pe awọn ọrọ ati iwaasu rẹ maa n da ariyanjiyan silẹ lori ikanni ayelujara ni gbogbo igba, nitori pe awọn ti ko din ni miliọnu lo n wo o.

Arabinrin kan ti wọn pe ni Ms Webb sọ pe ọmọ ọdun mẹrindinlogun ti ọwọ tẹ lo lọ tako Biṣọọbu naa lasiko ikọlu ọhun, ti wọn si lohun to sọ ko yatọ si ọrọ ẹsin.

Wọn ni gbogbo bi ọmọ naa ṣe ati ohun to sọ lo wa lori itakun ayelujara ṣọọṣi naa.

Ọmọkunrin naa ni nikan la gbọ pe o lọ koju Biṣọọbu naa, ati pe awọn ọlọpaa ni ko si ninu awọn ti wọn n wa nipa ẹsun ọdaran.

Wọn lọmọ naa ti wa nile iwosan nibi to ti n gba itọju, nitori ti wọn sọ pe oun naa fi ọwọ ṣeṣe.